Nibi ti ọkunrin yii ti fẹẹ ṣẹṣo owo l'aṣiri rẹ ti tu sita - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, July 3, 2023

demo-image

Nibi ti ọkunrin yii ti fẹẹ ṣẹṣo owo l'aṣiri rẹ ti tu sita

a4_1688306004

Ile-iṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Akwa Ibom ti sọ pe ọwọ awọn ti tẹ gendekunrin kan, Edu Ime lori ẹsun wi pe o n gbero lati ṣẹṣo owo ni ikorita, to si ti n ran an iṣẹ iwadii awọn lọwọ.
 
Ọga ọlọpaa ipinlẹ naa, CP Ọlatoye Durosinmi lo sọrọ naa jade lakoko to n f'oju Edu han f'awọn akọroyin lọjọ Ẹti, Furaide, ọsẹ to kọja yii ni olu ileeṣẹ wọn to wa lagbegbe Ikot Akpan Abia, niluu Uyo.
 
Nibẹ ni ọga ọlọpaa ọhun ti sọ pe ikorita Uraua Ekpa to wa lopopona marosẹ Calabar si Itu lọwọ ti tẹ ẹ ni nnkan bi aago mẹjọ kọja iṣẹju marun-un alẹ, lakoko to n ṣetutu lọwọ.
 
a6_1688305922

O ni ori oku to ti gbẹ, to fi n ṣetutu lọwọ ni wọn ka mọ-ọn lọwọ, ti ko si le ṣalaye idi ohun to n ṣe ni pato.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI

Contact Form

Name

Email *

Message *