Ko pẹ ti Ayọbami kuro l'ẹwọn oṣu meje lori ẹsun 'Yahoo-Yahoo', lo tun pada s'idi jibiti, lọwọ EFCC ba tẹ ẹ lẹẹkeji l'Ọyọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, July 15, 2023

Ko pẹ ti Ayọbami kuro l'ẹwọn oṣu meje lori ẹsun 'Yahoo-Yahoo', lo tun pada s'idi jibiti, lọwọ EFCC ba tẹ ẹ lẹẹkeji l'Ọyọ


Ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ajebanu lorileede Naijiria, Economic and Financial Crimes Commission, EFCC ti sọ pe ọwọ awọn tun ti tẹ gendekunrin kan ti ile-ẹjọ ti dajọ fun tẹlẹ lori ẹsun jibiti ori ayelujara ti a mọ si 'Yahoo-Yahoo', to si tun jẹ pe ko pẹ to jade lẹwọn lo tun pada s'idi iṣẹ jibiti ọhun.
 
Adeniran Ayọbami Tijesunimi ni wọn pe orukọ gendekunrin ọhun.

Oun pẹlu awọn mẹrinlelaadọta miran, ti awọn naa ko niṣẹ meji ju iṣẹ jibiti ori ayelujara lọ la gbọ pe ọwọ tẹ kaakiri ipinlẹ Ọyọ.
 
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ọjọ kẹẹdogun, oṣu keje, ọdun 2022 ni Onidajọ Uche Agomoh ti ile ẹjọ giga apapọ to wa niluu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ ju Ayọbami sẹwọn oṣu meje pẹlu iṣẹ aṣekara lori ẹsun 'Yahoo-Yahoo'.
 
Nigba naa, a gbọ pe Onidajọ Agomoh ko faaye sisan owo itanran silẹ fun Ayọbami, eyi to jẹ ko lo ẹwọn oṣu meje rẹ pe, ko to di pe wọn fi silẹ lati maa lọ sile.
 
Ọjọ kẹtala, oṣu keje ti a wa yii la gbọ pe ọwọ tun pada tẹ Ayọbami pẹlu awọn miran nigboro ilu Ọyọ, ipinlẹ Ọyọ.
 
Lara awọn tọwọ tẹ naa ni: Ademọla Saheed Adeniyi, Ọlayinwola Tomiwa Rokeeb, Moses Kehinde Biola, Adewale Mumini Adeyemi, Olowuoyin Qudus Atanda, Mojeeb Adedeji Olamilekan, Jonathan Emmanuel Opashi, Usman Abubakar Aruwa, Bamidele Olusoji Joseph, Daniel Anu Omyajowu, Olayinwola Dolapo Zacheous, Adekunle Daniel Adeniyi, Azeez Hammed Ademola, Olatunde Philip Bode, Lawal Abayomi Hammed, Adeniyi Sheu Abiodun, Abdulazeez Ifayemi Ayokunu, Adeleke Sunday Arise, Omiyale Tosin Akin, Segun Samuel Lekan, Popoola Oluwaseun Sunday, Jimoh Afeez Adewale, Bashir Qodir Yinka, Adedeji Ibrahim Ademola, Ajibade Samuel Femi, Omolulu Nurudeen Alabi, Victor Okotie Junior, Lateef Ridwan Aremu, Balogun Abisoye Isreal, Yusuf Alabi Toriola, Akinade John Damilare ati Suleiman Abdulrasaq.
 
Awọn yooku ni: Adeyẹwo Stephen Tomilọla, Ọkanlawọn Ọlanrewaju Qodir, Akinbola Ifafimihan Seun, Amusat Taofeek Opeyemi, Akintola Mojeeb Olakunle, Adebayo Malik Adigun, Dauda Rokeeb Opeyemi, Oladokun Abeeb Ajadi, Amusat Qowiyu Atanda, Usman Olatunji Badmus, Afonja Ifayemi Akano, Rokeeb Olamide Taiwo, Adebayo Gbawuga Oyetunji, Fasasi Olasunkanmi Qodir, Yekeen Gbolahan Samuel, Afolabi Ayodeji Emmanuel, Yekeen Micheal Opeyemi, Ayinla Mathew Opeyemi, Mikail Aliyu, Ajibola Nejeeb Pelumi, Bitrus Moses Bugama ati Eyamekware Gabriel Clevarly.
 
Foonu mọkandinlọgọrin (79), kọmputa alagbeka mẹrin, mọto bọginni meje ati awọn ẹru ofin miran ni wọn gba lọwọ gbogbo wọn nigba ti ọwọ palaba wọn segi.

Ajọ EFCC ti wa fidi rẹ mulẹ pe wọn yoo foju gbogbo wọn ba ile-ẹjọ lẹyin ti iwadii ba tubọ pari.




No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI