Kii ṣe gbogbo ẹbẹ araalu la n gbọ nileeṣẹ Dangote - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, July 20, 2023

Kii ṣe gbogbo ẹbẹ araalu la n gbọ nileeṣẹ Dangote


Awọn alaṣẹ ati alakoso ileeṣẹ Dangote to n ṣe simẹnti lorileede Naijiria, ẹka tiluu Ibeṣe ti sọ pe kii ṣe gbogbo ohun ẹbẹ ti awọn araalu ba kọ si wọn l'awọn dahun si, nitori pe eto ati ilana ileeṣẹ wọn pin si oriṣiriṣi.

Ọgbẹni Ademọla Ojolowo to jẹ alabojuto eto ohun to nii ṣe pẹlu araalu (Head of Brand Social Performance) nileeṣẹ naa to wa niluu Ibeṣe, ipinlẹ Ogun lo sọ eyi di mimọ nibi idanilẹkọọ ọlọjọ meji ti wọn ṣe fawọn akọroyin ipinlẹ naa.

Nigba to n sọrọ lori akọle to pe ni 'Social Performance in Dangote', ọkunrin naa ni ọpọ ojuṣe ni ileeṣẹ Dangote ti ṣe fun araalu bii atunṣe opopona, idagbasoke eto ẹkọ ati bẹẹ bẹẹ lọ.

O tẹsiwaju pe lara ojuṣe awọn nileeṣẹ Dangote ni lati mu ohun igbagbegbadun irọrun ba araalu, paapaa agbegbe ti ileeṣẹ wọn wa niluu Ibeṣe.

Ademọla Ojolowo ni oriṣiriṣi awọn eeyan lo n kọ iwe ẹbẹ si wọn lati ran wọn lọwọ, ṣugbọn to ni awọn ko le gba iwe naa wọle nitori ilana ati alakalẹ ileeṣẹ.

O ni alaṣẹ ati oludasilẹ ileeṣẹ naa, Aliko Dangote funra rẹ ni ajọ to ti n ran awọn eeyan lọwọ, eyi to pe ni Aliko Dangote Foundation, to si ni ọpọ awọn araalu lo ro pe ileeṣẹ wọn lo n bojuto ajọ yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI