Iwa ọmọluabi ṣe pataki pupọ - Ijọba Kwara gb'awọn agunbanirọ lamọran - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, July 19, 2023

Iwa ọmọluabi ṣe pataki pupọ - Ijọba Kwara gb'awọn agunbanirọ lamọran


Ijọba ipinlẹ Kwara labẹ Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti gba gbogbo awọn agunbanirọ patapata lorileede Naijiria lamọran lati mu itẹsiwaju ba orileede wọn ni oriṣiriṣi ẹka ti wọn mọ.
 
AbdulRazaq lo sọ eyi l'ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja yii niluu Ilọrin, iyẹn lakoko ti wọn n ṣayẹyẹ igbaniwọle f'awọn agunbanirọ ti onipele keji [Batch B] ti wọn dari wa si ipinlẹ naa.
 
Nigba to n gba ẹnu gomina sọrọ, igbakeji rẹ, Ọgbẹni Kayọde Alabi sọ pe ki awọn agunbanirọ naa ṣetan lati koju ipenija, fun ilọsiwaju Naijiria.

O ni ki wọn suro ṣinṣin, ki wọn si farabalẹ lati gba idanilẹkọọ ti wọn yoo kọ ni kaampu wọn, eyi ti yoo jẹ ki wọn koju awọn ipenija iṣẹ to wa niwaju wọn.

Bakan naa lo sọ pe ki wọn gbiaynju lati ṣe ara wọn ni aṣoju rere to ṣee f'ọkan tan fun mọlẹbi wọn ati ajọ agunbanirọ, nipa lilo iwa ọmọluabi.




No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI