Ipo Aarẹ lo kan ti mo fẹẹ du l'ọdun 2027 - Oguntoyinbo, oludije sipo gomina ipinlẹ Ogun lọdun 2023 - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, July 19, 2023

Ipo Aarẹ lo kan ti mo fẹẹ du l'ọdun 2027 - Oguntoyinbo, oludije sipo gomina ipinlẹ Ogun lọdun 2023


Odu ni Ambasadọ Olufẹmi Oguntoyinbo ninu ẹgbẹ oṣelu New Nigeria People’s Party (NNPP) nipinlẹ Ogun, oun ni oludije sipo Gomina nipinlẹ naa ninu eto idibo to kọja yii.

Bo tilẹ jẹ pe ipo ọhun ko ja mọ ọn lọwọ latari idi pataki kan to ṣalaye ẹ fun ikọ akọroyin ledee Yoruba, League Of Yoruba Media Practitioners, to gba lalejo lọfiisi rẹ n’Ibafo lọsẹ to kọja yii, Oguntoyinbo fi da gbogbo aye loju pe ijakulẹ to waye fun ti gomina ti lọ, o ni ipo aarẹ orilẹ ede yii loun yoo du ni 2027 pẹlu aṣẹ Oluwa.

Nigba to n fidi ẹ mulẹ pe ilu fẹ oun loye lasiko ibo to waye kọja naa, Oloye Oguntoyinbo to n dari ileeṣẹ Bullion Go-Neat Global Ltd, nibi ti wọn ti n ṣe ohun mimu amarale fawọn ọkunrin, ‘Coco-Samba’, sọ pe ẹni to jẹ alaga NNPP ipinlẹ Ogun nigba naa, Sunday Ọlapọsi Ọginni lo dalẹ.

O ni Ọginni lo ta oun pẹlu ẹgbẹ oṣelu NNPP fun PDP. Ọsẹ kan pere lo ku ki idibo waye ti Ọginni fi gbowo lọwọ awọn Ladi Adebutu gẹgẹ bi Oguntoyinbo ṣe wi, to si ni NNPP ti juwọ silẹ fun PDP, wọn ko dije mọ.

Bẹẹ, Oguntoyinbo ni irọ leyi. O ni Ọginni lo gbabọde, to ta oun oludije funpo gomina to si tun gbowo ori oun lai sọ kinni kan leti oun titi to fi gbe igbesẹ naa.

Ṣugbọn ẹṣin ki i da ni ka ma tun un gun, Ambasadọ Oguntoyinbo ṣalaye fawọn akọroyin pe ijakulẹ to kọja naa ti lọ, o ni eyi to ju ipo gomina lọ loun yoo gbegba rẹ ni 2027 b’Oluwa ba fẹ, iyẹn si ni ipo aarẹ orilẹ-ede yii.

‘’Oluwa lo pe mi pe ki n ṣiṣẹ fun orilẹ-ede yii, lati le yọ awọn eeyan kuro ninu iṣẹ ati oṣi. Nigba to ba di 2027, ipo aarẹ orilẹ-ede yii ni mo maa dije fun b’Ọlọrun ṣe ba mi sọ ọ, labẹ asia ẹgbẹ oṣelu NNPP yii naa si ni lagbara Oluwa’’

Oguntoyinbo sọrọ nipa iṣakoso Aarẹ Tinubu, o ni oun gbogbo n lọ bo ṣe yẹ ki Aarẹ ṣe e, nitori oṣelu ni baba naa, o si ti pẹ to ti n ba a bọ.

O tẹsiwaju pe oun pẹlu nifẹẹ lati ṣe ninu iṣejọba to n lọ lọwọ yii, nitori ifẹ araalu maa n jọba lookan aya oun lati ran awọn eeyan lọwọ, eyi lo ni o fa a toun fi da awọn ileeṣẹ silẹ loriṣiiriṣii tawọn eeyan n ṣiṣẹ oojọ nibẹ, bo tilẹ jẹ pe ki i ṣe ohun to rọrun lati da ileeṣẹ silẹ lorilẹ-ede yii.

Oguntoyinbo ni ifarajin faraalu maa n jẹ oun logun ni gbogbo igba, ohun to jẹ koun gbegba oṣelu lẹyin awọn iṣe yooku toun tun n ṣe bii abanikọle, ka ra ilẹ, ta ilẹ, ka gbe rẹkọọdu olorin jade, ka ko awọn elere idaraya lọ soke okun ati bẹẹ bẹẹ lọ niyẹn.

Nigba to n sọrọ lori atunṣe to yẹ ko wa nipa bo ṣe nira to lati da ileeṣẹ silẹ lorilẹ-ede yii, a ti idi ẹ ti awọn ileeṣẹ fi n kogba-wọle Ambasadọ Oguntoyinbo sọ pe awọn nnkan amayedẹrun tawọn onileeṣẹ ni i lo latọdọ ijọba ko si, bii ina ọba, bi ọna to ṣee rin geere. Owo dọla tun lagbara ju naira lọ, ti ko si beeyan yoo ṣe fi ra ọja wa sile nibi ti yoo pada pe,nitori ọrọ aje wa ti dẹnu kọlẹ. O ni bijọba yii ba le boju wo awọn nnkan wọnyi, ti wọn si dẹkun owo ori to pọ ju ni gbigba lọwọ awọn to n da ileeṣẹ silẹ, o ni o ṣee ṣe ki ọsan pada so didun fawọn eeyan ilẹ yii.

Bakan naa lo gba awọn oloṣelu nimọran, pe gbogbo ohun amayedẹrun ti wọn n ri niluu oyinbo ti wọn n lọ, ki wọn pese ẹ si orilẹ-ede tiwa naa letoleto, keeyan yee kerora ai rina ọba lo.

’’Ọdun kẹta ree ti mi o ti lo ina NEPA mọ, emi ni mo n pese ina ti mo n lo funra mi, nigba to jẹ wọn ko fun wa nina, mo ti ni ki wọn ka waya wọn kuro lọdọ mi. Eyi ko yẹ ko ri bẹẹ, bijọba Aarẹ Tinubu ba gba awọn ipinlẹ laaye lati pese ina ọba funra wọn, ki wọn tun ri i daju pe ileeṣẹ to n pese ina pọ si i, ko pọ bii tawọn ẹlẹrọ ibara-ẹni-sọrọ, kawọn eeyan le ra a nibi to wu wọn, eyi yoo din agbara awọn to wa nidii ẹ ku,yoo si jẹ ko rọrun faraalu’’ - Bẹẹ ni Ambasadọ Olufẹmi Oguntoyinbo wi.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI