Alaṣẹ ati oludasilẹ ijọ INRI Evangelical Spiritual Church, Wolii Babatunde Elijah Ayọdele, ti jẹ ko di mimọ pe gbogbo awọn oludije s'ipo aarẹ orileede Naijiria lọdun 2023 ti wọn lọ sile ẹjọ Tribunal ni wọn kan n da ara wọn laamu, ati pe bi ẹni to fẹẹ f'owo rẹ jona lasan ni.
Wolii Ayọdele sọ pe ko si nnkan rere ti yoo jade lati ile-ẹjọ Tribunal naa, bi ko ṣe pe niṣe ni wọn yoo pada da ẹjọ naa nu nigbẹyin, nitori pe idibo ti waye, o si ti lọ, ati pe ẹni to gbaradi l'awọn araalu dibo yan.
Gbajugbaja Wolii naa lo sọrọ yii lonii, ọjọ Abamẹta tii ṣe Satide, ọjọ kinni, oṣu keje, ọdun 2023, nibi eto akanṣe to ti maa n gbe iwe asọtẹlẹ ọlọdọọdun rẹ to pe ni ‘Warning To The Nations’jade.
Nibẹ lo ti sọ pe Aarẹ Tinubu gbaradi gidigidi lati di aarẹ ninu ẹmi, kii ṣe nipa ti oṣelu nikan, idi ree to fi sọ pe o jawe olubori lasiko idibo to kọja.
O ni awọn oludije to ku bii Alaaji Atiku Abubakar lati inu ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP ; ati Peter Obi toun jade lẹgbẹ oṣelu Labour ni wọn ko gbaradi bo ṣe yẹ.
Wolii naa sọ pe Atiku ati Obi ko gbajumọ oun to yẹ ki wọn gbajumọ, ati pe awọn nnkan ti ko le ṣe anfaani fun wọn, ni wọn n sare lepa rẹ lakoko naa, to si ni ohun to fa ijakulẹ wọn niyẹn.
No comments:
Post a Comment