Ibadan ni mo n gbe, Ijẹbu-Ode ni mo ti n ji eeyan gbe - Tunde Salami jẹwọ fun ẹṣọ aabo So-Safe Corps - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, July 16, 2023

Ibadan ni mo n gbe, Ijẹbu-Ode ni mo ti n ji eeyan gbe - Tunde Salami jẹwọ fun ẹṣọ aabo So-Safe Corps


Ileeṣẹ eleto aabo ipinlẹ Ogun ti a mọ si So-Safe Corps ti jẹ ko di mimọ pe ọwọ awọn ti tẹ ogbologbo ajinigbe kan ti orukọ rẹ n jẹ Tunde Salami, ẹni ọdun mejilelọgbọn.
 
Obinrin adelebọ kan, ti wọn lo n bọ lati ọja to ti lọ ounjẹ ti oun at'awọn mọlẹbi rẹ yoo jẹ la gbọ pe Tunde ati awọn ẹmẹwa rẹ jigbe loju ọna, ti wọn si tun gba gbogbo dukia ọwọ rẹ.
 
Goolu olowo nla, foonu ati ẹgbẹrun lọna ọgọrun kan naira la gbọ pe wọn gba lọwọ obinrin naa, koda ti wọn tun gba mọto obinrin naa pẹluu.
 
A gbọ pe niṣe ni wọn da obinrin naa lọna, ti wọn si wọ ọ bọ silẹ ninu mọto rẹ ni nnkan bi aago mẹwaa alẹ ọjọ kẹtala, oṣu keje, ọdun 2023 ti a wa yii.
 
Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe bi wọn ṣe wọ obinrin naa bọ silẹ, ni wọn ti gbe e si ẹyin mọto naa pẹlu idunkoko nla nipa awọn nnkan ija oloro bii ibọn ti wọn yọ si i.
 
Lẹyin ti wọn ṣe eyi la gbọ pe wọn gbe obinrin naa wọnu igbo, nibi ti wọn tun ti n dunkoko mọ ọn lati pa.
 
Asiko yii la gbọ pe awọn mọlẹbi obinrin naa ranṣẹ s'awọn ẹṣọ aabo So-Safe Corps wi pe wọn ti jii gbe wọnu igbo, ṣugbọn ti wọn sọ pe awọn oṣiṣẹ aabo naa ko le gbe igbesẹ nitori awọn idi kan ni pato.
 
Ko pẹ si asiko yii la gbọ pe awọn kan tun ta awọn oṣiṣẹ aabo yii lolobo wi pe awọn kofiri awọn ajinigbe kan ninu igbo, eyi lo mu ki wọn bẹrẹ iṣẹ iwadii loju ẹsẹ, ti aṣiri si tu si wọn lọwọ.

Agbẹnusọ fun ẹṣọ aabo So-Safe Corps naa, Ọgbẹni Mọruf Yusuf to gbe iroyin naa si wa leti sọ pe niṣe l'awọn ajinigbe yii daju ibọn kọ awọn oṣiṣẹ wọn nigba ti aṣiri wọn tu, ṣugbọn ti ọwọ pada tẹ Tunde laaarin wọn, nigba ti awọn yooku na papa bora.

Yusuf wa sọ pe Tunde ti jẹwọ f'awọn wi pe Ibadan loun ti maa n wa ji eeyan gbe niluu Ijẹbu-Ode, lai mọ pe aṣiri maa tu lọjọ kan.

O wa sọ pe ọga awọn, Sọji Ganzallo ti sọ pe k'awọn fa Tunde le awọn ọlọpaa lọwọ, to si l'awọn ti fa a le ọlọpaa ẹkun Ọbalende lọwọ lati tẹsiwaju iwadii wọn.
 
Yusuf tun jẹ ko ye wa pe awọn ti gba obinrin naa silẹ kuro lọwọ wọn, to si l'obinrin ọhun ti wa nibi to ti n gba itọju, ko to di pe o pada lọ sile l'ọdọ awọn mọlẹbi ẹ layọ ati alaafia.

Fọnran naa ree, nibi ti Tunde ti n jẹwọ:
 

 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI