David bẹ baba lanlọọdu ẹ lori danu l’Ogun, o tun ṣa ọga ọlọpaa niṣakuṣa (Fidio) - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, July 22, 2023

David bẹ baba lanlọọdu ẹ lori danu l’Ogun, o tun ṣa ọga ọlọpaa niṣakuṣa (Fidio)


Niṣe lọrọ di boo lọ o yago lọna laarọ ọjọ Ẹti tii ṣe Furaide to kọja yii, nigba ti wọn sọ pe gendekunrin, ẹni ọdun mejilelọgbọn kan, David Ṣhodọla deede ki ada mọlẹ, o si bẹ baba lanlọọdu ẹ, Alagba Alfred Ọpadipẹ lori danu.

Yatọ si Alagba Ọpadipẹ, ẹni ọdun mẹrilelọgọrin ti David bẹ lori danu yii, wọn lo tun ṣa ọga ọlọpaa ẹkun Ipara Rẹmọ, CSP Bankọle Iṣara Eluyẹru, ti wọn si ni ori lo ko o yọ lọwọ iku ojiji.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni aawọ kekere kan lo bẹ silẹ laaarin David ati pasitọ kan ti wọn jọ n gbẹ inu ile, ti wọn si ni Alagba Ọpadipẹ gbiyanju lati yanju ẹ fun wọn.

Lara awọn ara adugbo Ipara to wa n’ijọba ibilẹ Ariwa Rẹmọ, ipinlẹ Ogun ti iṣẹlẹ ọhun ti ṣẹlẹ to gbe iroyin naa si wa leti sọ pe o pẹ ti David ti maa n pariwo wi pe pasitọ naa maa n fi adura rẹ di oun leti.

Wọn ni gbogbo igba ti pasitọ yii ba ti n gbadura, ni David maa n sọ pe ariwo rẹ n di oun leti, ati pe ko gba ṣọọṣi lọ lati maa gbadura, ti wọn si ni pasitọ naa maa n sọ pe ẹmi eṣu lo n gbe inu ẹ.

Pupọ awọnn to sọrọ jẹ ko ye wa pe David ni aaganna diẹdiẹ, ti awọn eeyan ki i sii ẹ lati sunmọ, nitori ko ma ba a ṣe wọn ni jamba.

Nigba ti iṣẹlẹ naa waye, wọn ni pasitọ naa n gbadura lọwọ ninu yara rẹ, ni David sare wa lati ibi to wa, to si n gba ilẹkun rẹ wi pe bi ko ba dawọ adura rẹ duro, oun yoo pa a danu.


Bo ṣe n pariwo yii la gbọ pe Alagba Ọpadipẹ jade lati inu yara rẹ, to si ni ki David fi ẹni ẹlẹni silẹ, ati pe ko si nnkan to kan pẹlu aye alaye. Pẹlu ibinu ni wọn sọ pe David fi jade sita, to si lọ mu ada.

Ere ni wọn l’awọn eeyan kọkọ pe e, afi bo ṣe bẹrẹ sii fi ada ṣa baba naa, to si ṣa a titi to fi ge ori rẹ bọ silẹ. Ọpọ awọn ara adugbo ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn la gbọ pe wọn ko le sunmọ ibẹ, ti wọn si sare ranṣẹ s’awọn ọlọpaa ẹkun Ipara fun iranlọwọ.

K’awọn ọlọpaa too de ni wọn sọ pe David ti n dunkooko mọ awọn eeyan wi pe bi wọn ba fi le sunmọ oun, oun yoo ṣa wọn pa ni, nitori pe asiko ibinu loun wa.


Wọn ni b’awọn ọlọpaa ṣe debẹ ni David tun ti kọju ija si wọn, ti wọn si ro pe awọn le gba ada naa lọwọ ẹ. Ibi ti wọn l’awọn ọlọpaa yii ti fẹẹ gba ada lo ti ṣa ọga ọlọpaa, CSP Bankọle Iṣara Eluyẹru ladaa.

Eyi ni wọn lo jẹ ki wọn mọ pe ọrọ David ti kọja oju lasan, ti wọn si gbiyanju lati mu. Igba ti wọn rii pe agbara wọn ko fẹẹ ka a, ati bo ṣe n ṣe, lo jẹ ki wọn yinbọn fun un, ti ibọn naa si ran an lọ s’ọrun aremabọ.

Loju ẹsẹ la gbọ pe wọn ti sare gbe ọga ọlọpaa ti David ṣa lọ si ọsibitu aladani kan to wa nitosi fun itọju, ati lati doola ẹmi rẹ. Ibẹ si ni wọn sọ pe ọga ọlọpaa naa wa, to ti n gba itọju titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii.

Nigba to n f’idi rẹ mulẹ, Ọmọlọla Odutọla to jẹ agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ṣalaye wi pe awọn ara adugbo naa lo ranṣẹ pe awọn, lati fi iṣẹlẹ bi David ṣe pa alagba Ọpadipẹ to wọn leti.

O l’awọn ọlọpaa to lọ ro pe awọn le fi ọwọ lasan mu David ni, lai mọ pe o ti ya aja digbolugi, to si ṣa ọga to lewaju wọn lọ. Idi ree to fi ni wọn yinbọn pa a, lati le gba ada ọwọ ẹ, ko ma ba a tun ṣe ẹlomiran leṣe.

Odutọla ni iwadii t’awọn ṣe fi han pe David kii ṣe alagaana, ati pe iwa to wa ninu rẹ lo wu, ati pe o jẹ ẹnikan to fẹran wahala ati ijọgbọn ladugbo ọhun.



No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI