Baba arugbo, ẹni ọdun mẹtadinlọgọrin to n fipa ba ọmọ rẹ, ọmọ ọdun meje laṣepọ n’Ijẹbu-Ode sọ pe iṣẹ eṣu ni - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, July 16, 2023

Baba arugbo, ẹni ọdun mẹtadinlọgọrin to n fipa ba ọmọ rẹ, ọmọ ọdun meje laṣepọ n’Ijẹbu-Ode sọ pe iṣẹ eṣu ni

Abiọdun Alamutu, ọga ọlọpaa ipinlẹ Ogun
 
Beeyan ba ri bi baba agbalagba, ẹni ọdun mẹtadinlọgọrin tọwọ tẹ lori ẹsun ifipabanilopọ ṣe n wo pakopako ni olu ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Eleweran niluu Abẹokuta laipẹ yii ṣe n wo, yoo ro pe ko mọ nnkankan ni, ṣugbọn ti wọn sọ pe eṣu buruku lo n gbe inu ẹ.

Baba naa, Adedamọla Idowu, la gbọ pe ọwọ tẹ pẹlu ẹnikan ti wọn pe ni Oluwatobi Adebisi, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn ti wọn loun naa n f’ipa ba ọmọ ọhun laṣepọ.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni ọmọ ọdun meje to je ọmọ Adedamọla ni baba naa ba laṣepọ karakara, ko to di pe ọwọ tẹ ẹ.

Agbegbe Ijagun lọwọ ti tẹ awọn mejeeji lọjọ Ẹti tii ṣe Furaide, ọjọ keje, oṣu keje, ọdun 2023.

Ọga ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abiọdun Alamutu, sọ pe niṣe lawọn mejeeji sọ ọmọ ọdun meje naa di maṣiini ibalopọ, ti wọn si n fojoojumọ ba a laṣepọ, ko to di pe aṣiri wọn tu.

Alamutu sọ pe awọn ti bẹrẹ iwadii kikun, ati pe awọn ti mu ọmọ ọhun lọ si ibi ti wọn yoo ti tọju rẹ, ti wọn yoo si tun maa gba a niyanju, eyi to pe ni counseling and emotional therapy.

Bẹẹ lo fi kun un wi pe awọn mejeeji tọwọ tẹ yoo jẹ iyan wọn niṣu nigba ti wọn ba foju ba ile-ẹjọ lori iwa ọdaran naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI