Gbajugbaja onkọrin Juju nni, Ọmọwe Yinka Joel Ayefẹlẹ ni iroyin tun ti fi to wa leti wi pe o ti ṣi redio tuntun siluu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ.
Ayefẹlẹ lo ni ileeṣẹ redio Fresh FM to wa jakejado orileede Naijiria, eyi ti olu ileeṣẹ wọn wa niluu Ibadan.
Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe redio Tiwa-n-tiwa106.6FM ni Yinka Ayefẹlẹ tun ṣẹṣẹ da silẹ nigboro ilu Ibadan, ti wọn si ti bẹrẹ iṣẹ ni pẹrẹu.
Redio tuntun yii lo jẹ ki gbogbo ileeṣẹ redio ti Ayefẹlẹ ni di mẹjọ, awọn si ni;
Fresh 105.9fm (Ibadan),
Fresh 107.9fm (Abẹokuta),
Fresh 106.9fm (Ado Ekiti),
Fresh 104.9fm (Oṣogbo),
Fresh 105.3fm (Lagos),
Fresh 102.9fm (Akurẹ),
Blast 98.3fm (Ibadan) ati
Tiwa-n-Tiwa 106.6fm Radio (Ibadan).
No comments:
Post a Comment