B'awọn kan ṣe n kigbe ikunlẹ abiyamọ, bẹẹ l'awọn miran bẹrẹ adura agbayipo fun adajọ agba n'ipinlẹ Ekiti, Onidajọ John Adeyẹye, nigba ti wọn sọ pe apakan ogiri ọfiisi rẹ deede wo lulẹ, to si farapa yannayanna.
Iṣẹlẹ, b'awọn kan ṣe n sọ pe kii ṣe oju lasan, bẹẹ l'awọn miran n sọ pe sababi l'asan ni, t'awọn miran si n gbadura alaafia ati ẹmi gigun fun adajọ agba naa.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni nkan bi aago mejila aabọ ọsan niṣẹlẹ ọhun waye ninu ọfiisi rẹ to wa lagbegbe Fajuyi nilu Ado-Ekiti, ipinlẹ naa.
Ko pẹ ti wọn sọ pe Onidajọ Adeyẹye de inu ọfiisi rẹ, niṣẹlẹ naa waye, koda ti wọn sọ pe o n da awọn alejo lohun lọwọ, ko to lọ gbọ ẹjọ to wa nilẹ ni.
Wọn ni iṣẹlẹ yii lo dawọ gbogbo igbẹjọ to n lọ lọwọ duro, nitori pe niṣẹ l'awọn eeyan sare gbe baba naa lọ si ọsibiti aladani kan to wa nitosi fun itọju.
Lara awọn to fi iṣẹlẹ naa to wa leti sọ pe adajọ ọhun farapa gidigidi, ṣugbọn ti wọn lo ti n dahun si itọju ti wọn n fun un.
No comments:
Post a Comment