Ariwo ikunlẹ abiyamọ lo gba ẹnu ọpọ awọn ara agbegbe Sabo to wa niluu Ikẹbu-Ode, ipinlẹ Ogun nigba ti wọn gbọ pe baba agbalagba, ẹni ọgọta ọdun kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Tajudeen deedee gb'ẹmi ara rẹ.
Nnkan bi aago mẹrin aabọ irọlẹ ọjọ Ẹti, Furaide, ọsẹ yii ni wọn sọ pe baba naa to yan iṣẹ awọn to n tun ina mọnamọna ṣe, eyi ti a mọ si ẹlẹtiriṣian (electrician) gb'ẹmi ara rẹ lojiji
B'awọn kan ṣe n sọ pe asasi ni, bẹẹ l'awọn miran n sọ pe eedi ni, ti awọn miran si n ṣalaye pe ọrọ Naijiria lo suu, to fi wo o pe koun tete fi aye silẹ ko too pẹ ju.
Lara awọn to fi iṣẹlẹ ọhun to wa leti lo jẹ ka mọ pe ọdun meji sẹyin ni baba naa padanu iyawo rẹ, to si jẹ pe awọn ọmọ rẹ ko si nitosi.
Wọn ni niṣe ni baba yii n da gbe inu ile, to si jẹ pe iṣẹ ina titunṣe lo fi n jẹun.
Bo tilẹ jẹ pe titi di asiko yii l'awọn eeyan ko tii le fidi rẹ mulẹ nipa idi pataki to fi pokunso, sibẹ a gbọ pe bi nnkan ṣe ri lasiko yii lo fa a to fi ṣe bi akikanju ọkunrin.
Wọn ni bi epo rọbii ṣe lọ soke lojiji, ti gbogbo nnkan gbowo lori, lo fa a to fi pinnu naa.
Bẹẹ la gbọ pe iṣẹ ti baba yii yan laayo ko lọ deedee mọ, paapaa bi ko ṣe fi bẹẹ si ina mọnamọna niluu, to fa a ti atijẹun ṣe le koko fun un.
Awọn ara adugbo ti wọn ba oku baba naa loke to so ara rẹ kọ si ni wọn sare ranṣẹ s'awọn ọlọpaa lati wa a wo ohun ti oju wọn ri.
Wọn l'awọn ọlọpaa lo pada ja oku naa bọ silẹ pelu iranlọwọ awọn araadugbo, ko to di pe wọn gbe e lọ si mọṣuari ọsibitu ijọba to wa niluu Ijẹbu-Ode.
Gbogbo akitiyan lati ba agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Ọmọlọla Odutọla sọrọ lori iṣẹlẹ ọhun lo ja si pabo titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii.
No comments:
Post a Comment