Awọn eleyii ji iṣu wa, wọn tun lu oloko pa l'Ekiti - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, July 24, 2023

Awọn eleyii ji iṣu wa, wọn tun lu oloko pa l'Ekiti


Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti ti sọ pe ọwọ awọn ti tẹ ọrẹ mẹta kan ti wọn ko ni iṣẹ meji ju ole jija lọ, ati pe wọn tun lu baba agbalagba to da oko iṣu ti wọn lọ ji wa titi to fi ku.
 
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ naa, Sunday Abutu ṣalaye ninu atẹjade to gbe jade lonii, ọjọ Aje, Mọnde wi pe nnkan bi aago marun-in irọlẹ, ọjọ kejila, oṣu keje ti a wa yii ni wọn lọ ji iṣu oniṣu wa.
 
Abutu ni ẹni ti awọn mẹtẹẹta lọ sinu oko rẹ lati ji iṣu wa lo wa fi to awọn leti, ti wọn fi bẹrẹ iwadii, to si lọjọ keji, ọjọ kẹtala, oṣu yii lọwọ tẹ wọn ni nnkan bi aago meji.
 
Ogunlusi Damilọla, Ọlọrunṣọla Ṣẹgun, ati Ṣekoni Tunde l'awọn mẹtẹẹta naa tọwọ tẹ.
 
Abutu ni ẹni to wa f'ẹsun kan wọn naa sọ pe niṣe ni wọn yọ ada s'oun ninu oko oun to wa lopopona Iyin-Ado, Iyin Ekiti, toun si sa asala f'ẹmi ara oun. O nigba toun maa pada loun rii pe wọn ti ji iṣu oun ko salọ.
 
O nigba t'awọn n fọrọ wa wọn lẹnu wo, wọn jẹwọ pe otitọ ni, ati pe awọn ti kọkọ wọnu oko baba agbalagba ẹni ọdun marundinlaadọrun-un kan, Awẹ Taiwo Julius lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kẹfa, ọdun yii lagbegbe Ipọle-Ekiti.

Wọn ni b'awọn ṣe wọnu oko baba naa ni baba yii ti le wọn danu, ṣugbọn ti awọn koju rẹ, t'awọn si luu lalubami, ko to di pe awọn ji iṣu rẹ mẹwaa salọ.

Wọn l'awọn pada gbọ pe ọsibitu ijọba ipinlẹ Ekiti to wa niluu Ado-Ekiti ni baba naa dakẹ si.
 
Abutu wa jẹ ko wa pe awọn ti gba lara iṣu ti wọn jigbe lọwọ wọn, ati pe igbesẹ ti n lọ lati rọwọ to awọn yooku wọn, bẹẹ lo ni wọn yoo foju ba ile-ẹjọ lẹyin iwadii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI