Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii tan, ko tii daju pe awọn Baalẹ meji ti wọn ta ile ileeṣẹ redio ijọba ipinlẹ Ogun yoo bọ ninu iwa afọwọfa ati ojukokoro wọn yii.
Awọn Baalẹ naa, Ọlalekan Ọdẹmuyiwa ati Ṣẹgun Konigbagbe la gbọ pe wọn ta lara ilẹ redio ijọba ipinlẹ Ogun, iyẹn Ogun State Broadcasting Corporation, OGBC nitakuta f'awọn eeyan, ti wọn si tun n kọ dukia lori awọn ilẹ ọhun.
Ohun ti a gbọ pe ni pe hẹkita to le diẹ ni mẹrinlelogun (24.253 hectares) ni ilẹ naa to wa l'abule ọlọrunṣogo, lopopona Ọba niluu Abẹokuta, ijọba ibilẹ Ọbafẹmi Owode.
Wọn ni Ọdẹmuyiwa to jẹ Baalẹ abule Agejo ati Konigbagbe toun jẹ Baalẹ abule Ake ni wọn jọ pawọpọ lati maa ta awọn ilẹ naa, lai gba aṣẹ, ti wọn si n fowo ilẹ yii jaye familete ki n tutọ kaakiri igboro.
Yatọ si awọn meji yii, a gbọ pe awọn bii Wasiu Ogunṣina, ẹni ọdun mọkanlelaadọta; Kabiru Ọlafẹnwa; Babatunde Ọdẹmuyiwa, ẹni ọdun mọkanlelọgọta; ati Dare Awodele ni wọn jọ mọ nipa ọrọ ilẹ tita ọhun.
Nigba ti wọn n f'oju ba ile-ẹjọ Majisireeti to wa lagbegbe Iṣabọ niluu Abẹokutta l'ọjọ Ẹti tii ṣe Furaide to kọja yii, Onidajọ Morẹnikeji Ọṣibajo paṣẹ pe k'awọn ọlọpaa lọ ju wọn s'ọgba ẹwọn, titi digba ti wọn yoo fi ri esi gba lati ọdọ DPP, iyẹn Directorate of Public Prosecution.
Onidajọ Ọṣibajo sọ pe ọgbọn ọjọ ni awọn eeyan naa yoo lọ lọgbọn, ko to di pe igbẹjọ miran tun waye lọjọ kẹẹdogun, oṣu kẹjọ, ọdun 2023.
A gbọ pe awọn alakoso redio ipinlẹ Ogun ni wọn kọ iwe ẹsun si ijọba ipinlẹ naa lọjọ kọkandinlogun, oṣu kẹfa, ọdun 2023, wi pe awọn kan ti ta ilẹ wọn danu, ati pe wọn tun n dunkooko wi pe awọn ko le ṣe nnkankan lori ilẹ naa.
Awọn alakoso naa wa n rawọ ẹbẹ si ijọba lati di iranlọwọ lori bi wọn yoo ṣe gba gbogbo ilẹ wọn pada fun lilo ti wọn fẹ lo o fun.
Ṣaaju asiko yii, lọjọ ninu oṣu kin-in-ni, ọdun 2021 la gbọ pe awọn oloye ilu Ijẹmọ ti abule Agejo wa labẹ rẹ ti kọkọ rọ Ọdẹmuyiwa l'oye lori ẹsun iwa ilẹ tita lọna aitọ ati iwa afojudi.
Wọn ni niṣe ni ọkunrin naa n ta ilẹ onilẹ bo ṣe wu, to si n ṣi ipo rẹ lo, eyi lo mu ki igbimọ oloye ilu Ijẹmọ jawe lọ rọkun-ile fun Ọdẹmuyiwa. Wọn ni ọpọ igba ni wọn ti pe e lati wa a sọ idi to fi n ta ilẹ lọna aitọ, ṣugbọn ti ko dahun
Oluwo ilu Ijẹmọ to tun jẹ Aro ilu Ẹgba, Oloye Oluyinka Kufilẹ ninu atẹjade to gbe jade lọdun naa lo ti sọ pe awọn ko le foju fo awọn iwa afojudi naa mọ, fun idi eyi, o lawọn ko gbọdọ ri Ọdẹmuyiwa nibikibi lati maa pe ara rẹ ni Baalẹ abule naa mọ.
No comments:
Post a Comment