Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ti f'oju baale ile, ẹni ọdun marundinlogoji kan, Ayọmide Yusuf ti wọn fẹsun ole kan ba ile-ẹjọ Majisireeti to wa lagbegbe Iyaganku niluu Ibadan, ipinlẹ naa.
Ẹsun wi pe Yusuf ji Aguntan meji gbe ni wọn fi kan an niwaju Onidajọ O. A. Akande l'ọjọ Ẹti tii ṣe Furaidee, ọsẹ yii.
Bo tilẹ jẹ pe Yusuf sọ pe oun ko jẹbi pẹlu alaye, sibẹ Onidajọ Akande sọ pe ki wọn gba beeli rẹ pẹlu oniduro kan, ko si lọ san ẹgbẹrun lọna ogun naira.
Ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu karun-un, ọdun yii la gbọ pe Yusuf ji awọn Aguntan naa gbe ni nnkan bi aago mẹta aabọ ọsan ladugbo Ologunẹru to wa lagbegbe Alafara nigboro ilu Ibadan.
Wọn ni awọn Aguntan meji naa ko din ni ẹgbẹrun lọna ọgọta naira
Agbefọba Philip Amuṣan to fẹsun kan Yusuf niwaju ile-ẹjọ sọ pe ọkunrin kan to n jẹ Kayọde Okelabi lo so awọn ẹran rẹ mọlẹ, ki wọn ma ba a salọ, nibẹ si lo ti maa n fun wọn lounjẹ ati omi loore-koore.
Wọn ni bi Yusuf ṣe lọ tu awọn ẹran naa, to si n ko wọn salọ l'awọn ara adugbo rii, ti wọn si lee mu loju ẹsẹ. Nibẹ lo ti n bẹbẹ pe ki wọn daṣọ aṣiri boun, ati pe ki wọn foju aanu wo oun.
Awọn ara agbegbe naa ko gbọ, eyi lo mu ki wọn lọ fa a le awọn ọlọpaa lọwọ, ti wọn si wọ ọ lọ siwaju adajọ.
O sọ pe ẹsun ti ọlọpaa fi kan Yusuf yii lo tako iwe ofin ọdaran abala 390 (3) ati, 516 t'ipinlẹ Ọyọ tọdun 2000, to si lo ni ijiya ninu.
No comments:
Post a Comment