Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii la gbọ pe iṣẹlẹ ọhun ṣi n jẹ kayeefi, koda ti wọn sọ pe awọn eeyan ko le fi oju mejeeji sun mọ.
Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe awọn ajagungbalẹ yinbọn pa ọomọ ọdun mẹrinlelogun kan, Fẹmi ti wọn lo yan iṣẹ awọn to n ṣe omi sinu ile, iyẹn Plumber laayo.
Agbegbe ti wọn pe ni Orile Eegun Kara Nla to wa nitosi Mowe, ijọba ibilẹ Ọbafẹmi Owode, ipinlẹ Ogun ni wọn ti yinbọn pa Fẹmi, koda ti wọn sọ pe eeyan meji lo ti lọ si ija awọn ajagungbalẹ yii.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni abule ti ko dini ni mẹtala lawọn ajagungbalẹ yii ti gba niluu Ṣhimawa to wa nijọba ibilẹ Ṣagamu, ti wọnn si le awọn to n gbe nibẹ kuro.
Nnkan bi aago mejila ọsan ganri la gbọ pe awọn ajagungbalẹ ya wọ agbegbe naa, ti wọn si bẹrẹ sii lu awọn ti wọn ba nibẹ. Wọn ni bi wọn ṣe ri awọn agbaṣẹṣe ti wọn n ṣiṣẹ lọwọ, ni wọn ti dabọn bolẹ fun wọn.
Wọn ni bawọn janduku naa ṣe wọle, ni gbogbo awọn to n ṣiṣẹ lọwọ ti na papa bora, nibi ti wọn si ti n salọ ni ibọn ti ba Fẹmi, to si ṣubu lulẹ.
No comments:
Post a Comment