Ile-ẹjọ giga tiluu Abuja, eyi to wa lagbagba Gwagwalada niluu Abuja, olu-ilu Naijiria ti ju gendekunrin meji kan, Adegbayi Tunde Yusuf ati Emmanuel Ikenna Ogu sẹwọn lori ẹsun jibiti ori ayelujara ti a mọ si 'Yahoo-Yahoo'.
Ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kẹfa, ọdun 2023 ni Onidajọ A. Y. Shafa ju awọn mejeeji sẹwọn lọtọọtọ, lẹyin ti iwadii otitọ ti fẹsẹ mulẹ nipa ẹsun ti wọn fi kan wọn.
Ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ajẹbanu lorileede Naijiria, Economic and Financial Crimes Commission, EFCC, ẹka tiluu Abuja la gbọ pe wọn wọ awọn gendekunrin meji yii lọ sile ẹjọ lọjọ naa, pẹlu awọn ẹri gidi.
Nigba to n gbe idajọ kalẹ lori Yusuf, Onidajọ Shafa sọ pe lotitọ ni ọmọkunrin naa n pe ara rẹ ni orukọ Fillipo Marrazzo, ati pe ọmọ orileede Italy loun, eyi to fi n lu awọn eeyan ni jibiti lori ayelujara.
O ni o gba to to igba dọla lọwọ ẹnikan to n jẹ Sonia Maria, eyi to sọ pe o lodi s'ofin iwa ọdaran, to si ni ijiya ninu. Fun idi eyi, adajọ naa paṣẹ ko lọ fi ẹwọn oṣu kan pere gbara, tabi ko sanẹgbẹrun lọna igba naira gẹgẹ bni owo itanran lati fi rọpọ ẹwọn rẹ. Bẹẹ lo tun paṣẹ pe ki wọn lọ dana sun iPhone ti wọn gba lọwọ ẹ.
Ni ti Emmanuel, Onidajọ paṣẹ koun naa lọ lo ọsẹ meji pere lẹwọn, tabi ko san ẹgbẹrun lọna igba naira lati rọpo ẹwọn ẹwọn, ati pe ki wọn dana sun iPhone toun naa layika ile-ẹjọ.
Orukọ ti wọn pe ni Jayden Fields ni wọn loun fi n lu jibiti ati niṣe lo n sọ f'awọn eeyan pe oṣiṣẹ ologun loun.
No comments:
Post a Comment