Wọn ju Usman sẹwọn gbere l'Ekoo, ọmọ ọdun mẹjọ lo fipa ba laṣepọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, June 2, 2023

Wọn ju Usman sẹwọn gbere l'Ekoo, ọmọ ọdun mẹjọ lo fipa ba laṣepọ


Ile-ẹjọ to n gbọ nipa ẹsun to nii ṣe pẹlu ibalopọ nipinlẹ Ekoo, Sexual Offences and Domestic Violence ti ju baale ile, ẹni ọdun mejilelogoji kan, Suleimon Usman sẹwọn gbere lori ẹsun ifipabanilopọ.
 
Omọ ọdun mẹjọ, to jẹ ọmọ rẹ ni iroyin fi to wa leti pe Usman fipa ja ibale rẹ, ti aṣiri rẹ si tete tu sita.
 
Esun meji ọtọọtọ to nii ṣe pẹlu ifipabanilopọ la gbọ pe wọn fi kan Usman, ṣugbọn ti Onidajọ Rahmon Oshodi daa lare lori ẹsun  keji.
 
Esun akọkọ ti wọn fi kan Usman la gbọ o sọ pe oun jẹbi rẹ, ṣugbọn Onidajọ Oshodi sọ pe dandan ni yoo ṣẹwọn rẹ, nitori pe ẹri toun ri gba kọja ohun ti wọn le fọwọ bo.
 
Agbefọba Inumidun Ṣolarin, to tako Usman mu ẹlẹri mẹrin ọtọọtọ wa jẹrii niwaju adajọ, awọn si ni ọmọ ọdun mẹjọ naa, iya ọmọ yii, iwe ẹri dọkita ati ọlọpaa to wa lakoso ẹjọ naa.
 
Ṣolarin sọ pe ẹsun ti wọn fi kan Usman lo tako iwe ofin ọdaran ti abala 137 tipinlẹ Ekoo  lọdun 2015, to fi si ni ijiya ninu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI