Wọn ju Adeoye sẹwọn n'Ilọrin, Cash App lo fi n lu jibiti lori ayelura - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, June 24, 2023

Wọn ju Adeoye sẹwọn n'Ilọrin, Cash App lo fi n lu jibiti lori ayelura


Ile-ẹjọ giga tipinlẹ Kwara ti ju gendekunrin mẹta kan ti wọn ko niṣẹ meji kọja jibiti ori ayelujara ti a mọ si 'Yahoo-Yahoo' sẹwọn pẹlu iṣẹ aṣekara.
 
Onidajọ Adebayọ Yusuf lo ju awọn mẹta naa, Aṣaolu Fẹmi Richard, ẹni ti wọn lo yẹn iṣẹ awọn to n tun gbọngan ati gbagede ariya ṣe, eyi ti a mọ si 'Event Decorator' laayo; Adeoye Abdulgafar Ọlaṣhile ati Madiu Bayọ Tajudeen sẹwọn lori ẹsun iwa jibiti.

Ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ajẹbanu lorileede Naijiri, Economic and Financial Crimes Commission, EFCC, lo wọ mẹtẹẹta wọnyii lọ siwaju ile ẹjọ pẹlu ẹsun ọtọọtọ.

Aṣaolu ni wọn loo jẹ bibi ilu Ilọffa to wa nijọba ibilẹ Oke-Ero, ipinlẹ Kwara; nigba ti Adeoye ati Madiu wa lati ijọba ibilẹ Atiba ati ijọba ibilẹ Kiṣhi n'ipinlẹ Ọyọ.

Wọn ni orukọ oyinbo, ọmọ ilẹ Texas lorileede United Kingdom to n jẹ Marissan Hant ni Aṣaolu fi n lu jibiti lori ayelujara, bẹẹ lo tun n lo imeeli [email protected] fi gba owo.

A gbọ pe o gba ọgbọn dọla lowọ ẹnikan to n jẹ Nick Fansier, ninu oṣu kẹrin ọdun yii, ẹsun ti wọn lo tako iwe ofin ọdaran orileede yii labala 321 to si ni ijiya labala 324.
 
Adeoye ni tiẹ la gbọ pe laaarin oṣu kọkanla, ọdun 2022 si oṣu kẹrin, ọdun 2023 loun lu jibiti irinwo-ataabọ $450 owo dọla. Orukọ oyinbo nni, Farmer Daughter lo fi lu jibiti owo naa lori ikanni ti wọn pe ni Cash App.

Ni ti Tajudeen toun naa n lo orukọ Sylvia lo lu jibiti laaarin oṣu kọkanla, ọdun 2022 si oṣu kẹta, ọdun 2023. ẹgbẹta owo dọla la gbọ pe oun lu jibiti rẹ.
 
Onidajọ Yusuf nigba to n gbe idajọ naa kalẹ ṣalaye pe awọn ẹri toun ri gba kọja nnkan ti wọn le dawọ bo, fun idi eyi, o ni ku Aṣaolu lọ fẹsun oṣu mẹfa gbako jura, tabi ko san ẹgbẹrun lọna ọgun-un naira gẹgẹ bi owo itanran, ko si gbagbe foonu Samsung S10 ati owo to lu jibiti ẹ sọwọ ijọba.
 
Ẹwọn oṣu mẹfa naa ni Onidajọ Yusuf ju Adeoye si pẹlu owo itanran ẹgbẹrun lọna aadọta naira, bẹẹ loun naa yoo gbagbe foonu iPhone 13 Pro Max ati owo to lu jibiti ẹ sọwọ ijọba.
 
Idajọ naa ko yatọ fun Madiu, ẹni ti wọn ju sẹwọn oṣu mẹfa pẹlu iṣẹ aṣekara, toun naa si lanfaani si owo itanran, ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un naira. Oun naa yoo gbagbe foonu Samsung S8 ati kọmputa alagbeka HP ati owo to lu jibiti ẹ sọwọ ijọba.



No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI