Ijọba ipinlẹ Ekoo labẹ Gomina Babajide Sanwo-Olu ti sọ pe oun fun gbajugbaja oṣerebinrin nni, Iyabọ Ojo ni ọjọ meje pere lati san gbese owo ori miliọnu mejidinlogun ataabọ (N18, 640, 092.00) naira.
Wọn ni lati ọdun 2021 ni Iyabọ Ojo ti kọ lati san owo ori lori ileeṣẹ ati ile rẹ to n gbe, ti owo naa si din diẹ ni miliọnu mọkandinlogun naira.
Ninu lẹta ti ijọba Ekoo fi ranṣẹ si ilu-mọ-ọn-ka oṣerebinrin naa laipẹ yii ni wọn ti jẹ ko di mimọ pe lọdun 2021 ni Iyabọ jẹ gbese miliọnu mọkanla le diẹ ₦11,264,092 naira.
Bẹẹ ni wọn lo tun jẹ gbese miliọnu meje le diẹ ₦7,376,000 naira fun ọdun 2022 to kọja.
Ọjọ meje pere ni ijọba Ekoo ni ki obinrin yii fi san gbese naa, ko to di pe wọn gbe igbesẹ to tọ labẹ ofin.
Lẹta naa ree:
No comments:
Post a Comment