Aarẹ Bọla Ahmẹd Tinubu ti ṣe ipade papọ pẹlu gbogbo awọn Gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC niluu Abuja, fun ajọṣepọ to dantọ.
Ọjọ Ẹti tii ṣe Furaidee, ọsẹ yii ni Aarẹ Tinubu b'awọn gomina ọhun ṣepade papọ nile agbara orileede yii to wa niluu Abuja, iyẹn Aso Rock.
Lara awọn gomina to wa nibẹ ni Alaga ẹgbẹ awọn Gomina, Malamu Abdulrahman Abdulrazaq tipinlẹ Kwara; Babajide Sanwo-Olu tipinlẹ Ekoo; Dapọ Abiọdun tipinlẹ Ogun; Hope Uzodimma tipinlẹ Imo; Abdullahi Sule tipinlẹ Nasarawa; Umar Namadi tipinlẹ Jigawa; Inuwa Yahaya tipinlẹ Gombe; atawọn miran.
No comments:
Post a Comment