Bi ayẹyẹ ọdun Ileya ti awọn Musulumi kaakiri agbaye maa n ṣe, ṣe ti sunmọ etile, gbajugbaja ileeṣẹ ADRON HOMES to n ta ilẹ, ile ati dukia ti sọ pe awọn fẹẹ fi ẹbun tọrẹ fawọn araalu.
Irọrun lo ba de bayii fun gbogbo awọn eeyan kaakiri agbaye lati jẹ anfaani ti ko wọpọ, eyi ti ileeṣẹ Adron Homes and Properties Limited ṣagbekalẹ rẹ, lojuna lati jẹ k'awọn eeyan di lanlọọdu ati lanladi.
Anfaani ọhun ni wọn pe ni 2023 SALLAH RẸPẸTẸ, eyi ti yoo jẹ k'awọn eeyan ti wọn n foju sọna lati di onile lori ni ipin, ki ipinnu wọn le wa si imuṣẹ laipẹ jọjọ.
Odu ni ileeṣẹ Adron Homes and Properties Limited lorileede Naijiria, ati kaakiri gbogbo agbaye nibi ka ta ilẹ, ile ati dukia. Yatọ si pe wọn n ta ilẹ, bẹẹ ni wọn tun n ba awọn onibara wọn kọ ile to jọju, ile awoṣifila sibi ti wọn ba fẹ.
Gẹgẹ bi aṣe gbọ, ileeṣẹ Adron ti ja owo ilẹ wọn wa silẹ pẹlu iye to jọju, ti wọn si ni anfaani yii, fun asiko perete ni, nitori ayẹyẹ ọdun Ileya to wọle de.
Ninu atẹjade awọn alakoso ileeṣẹ naa fi sita, eyi ti ẹda rẹ tẹ AWIKONKO lọwọ laipẹ yii, ni wọn ti jẹ ko di mimọ pe kii ṣe fun awọn Musulumi nikan ni anfaani yii wa fun, bi ko ṣe gbogbo eeyan ti wọn ba ni erongba lati di onile lori.
Wọn ni gbogbo ẹni to ba n fẹ lati kuro ninu ẹgbẹ ayalegbe, ti wọn fẹẹ ju kọkọrọ ile onile silẹ, ni wọn le darapọ lati kopa ninu anfaani alailẹgbẹẹ naa.
Lara awọn anfaani ti awọn onibara yoo jẹ ni ti ida ọgbọn (30%), ida ogoji (40%) ati ida aadọta (50%) ti wọn yoo jẹ lori gbogbo ilẹ ti wọn ba ko owo le lori.
Kii ṣe ẹẹkan ṣoṣo ni awọn eeyan le san owo ilẹ ti wọn ba ra. A gbọ pe awọn to ba ra ilẹ le lo ọgbọn oṣu (30 Months) lati fi san owo ilẹ wọn tan ni gbogbo ibi ti ileeṣẹ ADRON ni ilẹ si n'ipinlẹ Ekoo, Ogun, Ọṣun, Ọyọ, Ekiti, Niger, Nasarawa, to fi mọ ilu Abuja.
Ninu atẹjade naa ti alakoso eto tita ati ipolongo ileeṣẹ ADRON, Olubunmi Akinfẹ bu ọwọ lu, o sọ pe ọdọọdun ni anfaani bayii maa n ṣi silẹ, ati pe tọdun yatọ si awọn eyi ti wọn ti ṣe kọja lọ, to si ni irọrun leleyii ba de.
Bakan naa lo fi kun ọrọ rẹ wi pe awọn onibara yoo ni anfaani lati tun gba awọn ẹbun bii Baagi Irẹsi Agbo ọdun Ileya, Ewurẹ, Faanu, Amohundungbẹmu inu ile, ọhun igbomilena igbalode, water dispensers, electric kettles, refrigerators, food processors, vacuum cleaners, bags of rice, cooking oil, gas burners, mini food packs, washing machines, deep freezers, smart TVs, generators ati bẹẹbẹẹ lọ.
Siwaju sii lo tun fi kun ọrọ rẹ pe aarin asiko ti ẹ n ka iroyin yii, titi di ipari oṣu kẹjọ, ọdun 2023 ni anfaani naa yoo fi waye fun gbogbo awọn onibara atijọ ati awọn onibara tuntun lai yọ ẹnikẹni silẹ.
No comments:
Post a Comment