Ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ajẹbanu lorileede Naijiria, Economic and Financial Crimes Commission, EFCC, ẹka tiluu Ilọrin, ipinlẹ Kwara ti foju pasitọ ijọ Living Faith Church, ti a mọ si Winners Chapel, Temidayọ Eseyin, ba ile-ẹjọ giga t'ipinlẹ naa lori ẹsun iwa jibiti.
Owo to le diẹ ni miliọnu mọkandinlogun miliọnu N19.3m naira la gbọ pe Temidayọ lu fasiti Landmark to wa niluu Omu-Aran ni jibiti rẹ, ti aṣiri rẹ si tu sita.
Amofin ni wọn pe Temidayọ, ti wọn si lo wa lara awọn ibimọ to amuṣẹṣe nipa titẹle ilana ofin egbe naa, eyi ti a mo si Disciplinary Committee, iyẹn lẹka tiluu Ilọrin.
Ẹsun mẹrin ọtọọtọ to nii ṣe pẹlu aiṣootọ, aṣilo ipo ati jibiti ni ajọ EFCC fi kan Temidayọ niwaju ile-ẹjọ giga tiluu Ilọrin.
Ninu iwe ẹsun ti kọ ranṣẹ si ajọ EFCC, wọn sọ pe amofin to n ṣiṣẹ pẹlu fasiti naa ni Tmidayọ, ti wọn si gbe awọn dukia kan si ikawọ rẹ lati maa mojuto o.
Wọn ni awọn iwe, owo ati dukia to jẹ ti fasiti Landmark niluu Omu-Aran naa lo ni anfani si. Lara rẹ ni wọn sọ pe ile kan ti wọn n pe ni "Old Midland Building" to jẹ ti fasiti yii, to wa lopopona Emir si Obbo niluu Ilọrin ni Temidayọ ya awọn eeyan, to si n gba owo rẹ lati bi ọdun mẹjọ sẹyin.
Fun gbogbo ọdun mẹjọ yii ni wọn sọ pe Temidayọ ko ko owo kankan silẹ f'awọn alaṣẹ fasiti, to si jẹ pe ko ni akọsilẹ nigba ti wọn beere owo lọwọ rẹ. Aarin ọdun 2014 si 2022 ni wọn sọ yii.
Wọn ni igba ti Temidayọ n gbiyanju lati lu ile naa ta ni gbanjo ni aṣiri rẹ tu s'awọn alakoso fasiti naa lọwọ, ti wọn fi lọ fa a le awọn ajọ EFCC lọwọ
Nigba ti Temidayọ n sọ niwaju ile-ẹjọ wi pe oun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan oun, agbẹjọro ajọ EFCC, Rashidat Alao, rọ ile-ẹjọ lati mu ọjọ miran ti igbẹjọ yoo waye, to si ni ki ile-ẹjọ paṣẹ pe k'awọn ṣi fi pamọ sọgba ẹwọn titi digba naa.
Agbẹjọro Temidayọ ni tiẹ, Fẹmi Makinde, bẹbẹ pe ki ile-ẹjọ fun onibara oun lanfaani beeli titi digba ti igbẹjọ miran yoo tun pada waye.
Onidajọ Lawal wa gba ẹbẹ naa, to si paṣẹ pe ki wọn gba beeli Temidayọ pẹlu miliọnu mẹwaa naira ati oniduro meji ọtọọtọ ti ẹnikọọkan yoo san miliọnu naira.
Bakan naa ni Onidajọ sọ pe awọn oniduro yii gbọdọ ni dukia ti ko jinna si ayika ile ẹjọ, ati pe ki Temidayọ ṣi wa lahamọ titi digba ti yoo fi ri awọn ẹlẹri naa.
No comments:
Post a Comment