Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ti sọ pe mẹta ninu awọn mẹrin to n digunjale kaakiri igboro ilu Ibadan lọwọ awọn ti tẹ bayii, ti wọn si ti n da gbogbo t’ẹnu wọn silẹ nipa bi wọn ṣe n ṣiṣẹ idigunjale wọn.
Awọn mẹta yii la gbọ pe wọn pa ọkunrin kan, Makanjuọla Ogedengbe, bẹẹ ni wọn tun fipa ba awọn ọmọ rẹ meji ti ọjọ ori wọn ko ju ọdun mẹwaa ati mẹrinla laṣepọ karakara lọjọ ti wọn lọ digun ja wọn lole.
Nigba to n foju wọn han f’awọn akọroyin lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii, Adewale Ọṣifẹsọ to jẹ agbẹnusọ f’awọn ọlọpaa ṣalaye pe agbegbe Apaataku si Onireke ni Akobọ, Ibadan ni wọn ti lọ digunjale lọjọ kẹrinla, oṣu karun-un, ọdun yii.
O ni ṣe ni wọn ja ọpọ awọn ara agbegbe naa lole, ṣugbọn nigba ti wọn de ile Adekusibẹ, wọn ko ri ohunkohun gba, eyi lo jẹ ki wọn pa ọkunrin naa, ti wọn tun fipa ba awọn ọmọ rẹ laṣepọ.
Siwaju sii lo ni awọn ara agbegbe naa lo wa fiṣẹlẹ ọhun to wọn leti, ko to di pe ẹka ileeṣẹ wọn, SCID ni Iyaganku gba iṣẹ iwadii naa ṣe.
Bakan naa lo sọ pe awọn mẹrin yii tun lọ digunjale lagbegbe Sawia Estate to wa ni Ọgbẹrẹ niluu Ibadan lọjọ kẹrindinlogun, oṣu kẹrin, ọdun yii, ti awọn ọlọdẹ si pa ọkan lara wọn danu.
O ni ninu iwadii lọwọ ti tẹ Ibrahim Rasaq, Abiọdun Ọlalekan ati Abọlade Morẹnikeji. Igba ti wọn fọrọ wa wọn lẹnu wo ni aṣiri tun ti tu sita pe awọn ni wọn lọwọ si bi wọn ṣe pa Adekusibẹ, ti wọn si tun b’awọn ọmọ rẹ meji laṣepọ.
Abọlade Morẹnikeji ati Sọdiq ti wọn loun ni olori wọn, ẹni ti wọn pa danu nibi ti wọn ti lọ jale la gbọ pe wọn fipa ba awọn ọmọ naa laṣepọ.
Ninu ọrọ agbẹnusọ ọlọpaa Ọṣifẹsọ ṣalaye pe awọn ọdaran naa jẹwọ pe ọwọ tun tẹ ẹnikan to n jẹ Adebayọ Salami, ẹni to maa n ṣe agbodegba ati alami fun wọn, to si tun maa n gba ẹru ti wọn ba jigbe.
O ni gbajugbaja lanlọọdu ni Addebayọ Salami lagbegbe Ajara Ọlọhunda, Akobọ niluu Ibadan, toun naa si ti n ṣalaye idi to fi pẹlu wọn.
Wọn loun gan-an lo ranṣẹ pe wọn lati wa jale ni Apatuku lọjọ ti wọn fipa ba ọmọ meji naa laṣepọ, ti wọn tun pa baba wọn danu.
No comments:
Post a Comment