Ọwọ ọlọpaa tẹ ogbologbo adigunjale mẹfa l'Ọṣun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, June 23, 2023

Ọwọ ọlọpaa tẹ ogbologbo adigunjale mẹfa l'Ọṣun


Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ti sọ pe ọwọ awọn ti tẹ awọn gendekunrin mẹfa kan ti wọn ko niṣẹ meji ju idigunjale lọ, ati pe o ti pẹ ti awọn ti n wa wọn.
 
Agbẹnusọ f'awọn ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun, Yẹmisi Ọpalọla lo sọ pe eyi di mimọ nigba to n f'oju awọn mẹfa naa han f'awọn akọroyin lonii, Ọjọbọ tii ṣe Tọsidee, niluu Oṣogbo.

Ọpalọla sọ pe ọjọ kẹẹdogun, oṣu kẹfa, ọdun 2023 ti a wa yii ni ọwọ tẹ awọn eeyan naa, lẹyin ti ẹnikan lọ fi ẹjọ sun awọn ọlọpaa ẹkun Gbọngan niluu Ibadan.
 
Ibrahim Yusuf, ẹni ọdun mẹrinlelogun; Lawal Abubakar, ẹni ọdun marundinlọgbọn; Umar Abubakar, ẹni ọdun mardinlogoji; ati Sule Muhammed, ọmọ ogun ọdun, lawọn tọwọ tẹ naa.
 
Awọn meji yooku ni Salisu Ismail, ẹni ọdun mọkanlelọgbọn ati Habeeb Saudi, toun jẹ ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn, ti wọn lo n gba ẹru ti wọn ba jigbe.
 
Ọpalọla ninu ọrọ rẹ ni;
“Ni nnkan bi aago mẹfa aabọ aarọ, ọjọ karundinlogun, oṣu kẹfa, ọdun 2023, ẹnikan wa fi ẹjọ sun ni ẹkun ti Gbọngan wi pe ni nnkan bi aago kan ọjọ naa, oun gbe awọn mẹrin kan ni ero lati garaaji Opic nipinlẹ Ogun, ti wọn si n lọ si Abuja pẹlu Mercedez Benz ti ko ni nọmba idanmọ.
 
“Ṣugbọn bi wọn ṣe de agbegbe Ikire, awọn toun gbe fipa ja oun bọ silẹ ninu mọto toun fi gbe wọn, ti wọn si tun dabọn bolẹ foun. Nibi to ti n ba wọn jijakadi, wọm yọ ibọn jade, wọn si fi gun un lọwọ osi rẹ, ti wọn si gbe mọto naa salọ.
 
“Ọkunrin naa n i boun ba ri oju awọn mẹrin naa, oun le da wọn mọ daadaa. Loju ẹsẹ si ni iwadii ti bẹrẹ. Ọkunrin yii ko tii kuro ni teṣan ti wọn fi pe wi pe awọn ọlọpaa da mọto kan duro loju ọna Ibadan si Ile-Ifẹ, ati pe gbogbo awọn to wa ninu ẹ lo sa bọ silẹ, ti wọn si na papa bora.
 
“Awọn ọlọpaa ko foju aanu wo wọn, ti wọn fi sare tẹle wọn wọnu igbo, tọwọ si tẹ meji ninu wọn lakoko naa. Lara iwadii to tẹsiwaju lo jẹ ki ẹka to n ri sọrọ ijinigbe fi tọpinpin awọn yooku de ilu Ekoo, ti ọwọ si tẹ wọn.”
 
Ọpalọla ni iwadii ṣi n tẹsiwaju.
 


 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI