Ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ajẹbanu lorileede Naijiria, Economic and Financial Crimes Commission, EFCC, ẹka tiluu Ibadan ti sọ pe ọwọ awọn ti tẹ oṣiṣẹ ọsibitu ijọba apapọ Federal Medical Centre, Idi-Aba, Abeokuta, ipinlẹ Ogun, iyẹn Balogun Ọlawale, lori ẹsun jibiti.
Yatọ si Ọlawale tọwọ tẹ, ọwọ tun tẹ gendekunrin mẹtadinlaadọta miran ti a gbọ pe wọn ko niṣẹ meji ju jibiti ori ayelujara ti a mọ si Yahoo-Yahoo lọ.
Ọjọru tii ṣe Wẹsidee to kọja, ọjọ kẹrinla, oṣu kẹfa, ọdun yii ni ajọ EFCC sọ pe ọwọ awọn tẹ awọ eeyan naa kaakiri ilu Abẹokuta.
Lara awọn eeyan naa ni Sọdiq Iremide, Abiọna Solomon, Mọshood Ṣakiru Ọlamide, Ọlalekan Sọdiq Ọlawale, Adebayọ Ifẹoluwa Timilẹhin, Joshua Gilbert, Adeleke Oluwafẹmi, Lawal Yusuff Abiọdun, Ọlalẹyẹ Adedọlapọ Emmanuel, Ọpalẹyẹ Ọlanrewaju, Kazeem Ọladimeji, Akinlosotu Ayọdeji Ayọmipọsi, Ọmọwale Haruna, Akinsolotu Kọlade Ọlayinka, Ṣorẹmikun Ibrahim, Kọlawọle Boluwatifẹ Daniel, Olufunkunmi Emmanuel, Ọlatunji Uthman Alabi, Afeez Jimọh Akorede, Lateef Abdulmujeeb Akanbi, Bọladalẹ Ọlajide James ati Ẹnitan Tolulọpẹ John.
Awọn yooku ni Ọrunṣolu Sọdiq Babatunde, Lamidi Micheal Akọlade, Lateef Rahamọn Ọlamilekan, Idowu Micheal Oluwaṣẹgun, Peter Adio Ọlakunle, Ahmọd Kazeem Ọlayẹmi, Okewọle Daniel Ọlayiwọla, Ogundẹyin Faruq Ọlamilekan, Ẹdunjọbi Tọheeb Ayọbami, Simon Dare Tosin, Ahmọd Mustapha Ọlawale, Ọladẹinde Mubarak Ọlanṣile, Ọlanrewaju Kabiru Ọlamilekan, Olowookere Abeeb Lọlade, Dọlaoṣo Uthman Ọlamilekan, Kodagbese Emmanuel Aduragbemi, Simon John Ṣeyi, Idemudia Lucky, Ahmọd Waheed Ọlamide, Olowookere Ṣoburu Ademọla, Agboọla Ọladimeji Taofeek, Awoniyi Ṣẹgun Gbenga, Babatunde Mathew Ayọdele, Alaye John Saheed ati Ọdẹdiran Oluwọle Ayọmide.
Lara awọn ẹru ti wọn gba lọwọ wọn ni mọto bọginni meje ọtọọtọ, kọmpta alagbeka loriṣiriṣi, foonu olowo ati aago ọwọ nla rẹpẹtẹ ati awọn nnkan miran.
Ninu iroyin miran la ti gbọ pe ọwọ tun tẹ awọn afurasi ọmọ Yahoo meji nigboro ilu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ.
Agbegbe ti wọn pe ni Idi-Igba lọwọ ti tẹ awọn meji naa ti orukọ wọn n jẹ Adeniji Samson Adebayọ ati Ayoọla Ọlawale Samson. Mọto meji ati awọn nnkan miran ni wọn gba lọwọ awọn naa, iyẹn l'Ọjọru, Wẹsidee kan naa yii.
Bakan naa ni ajọ EFCC tun sọ pe ileeṣẹ ọlọpaa rọwọ to Andrew Ọlasunkanmi ti wọn loun naa n lu jibiti ori ayelujara, ti wọn si ti fa a le awọn lọwọ, pẹlu mọto Honda Civic ati awọn foonu ti wọn gba lọwọ ẹ.
EFCC fi kun ọrọ rẹ wi pẹ awọn yoo fa awọn afurasi ọdaran yii lọ siwaju ile ẹjọ lẹyin ti iwadii awọn ba pari.
No comments:
Post a Comment