Oriire nla lo de ba ileeṣẹ Pelican Valley to n ta ilẹ, ile ati dukia kaakiri ipinlẹ Ogun pẹlu bi wọn ṣe gba gbajugbaja amofin nni, Arabinrin Aminat Ọlabisi Adisa gẹgẹ bi akọwe ileeṣẹ wọn.
Bi wọn ba n ka awọn ileeṣẹ to n ṣoowo ilẹ ati dukia tita lorileede Naijiria, paapaa nilẹ Yoruba lasiko yii, ọkan pataki ni ileeṣẹ Pelican Valley Nigeria Limited jẹ, nitori iwa ọmọluabi ti wọn fi n ṣe ni gbogbo igba.
Gẹgẹ bi atẹjade ti alakoso eto (Director of Operations) ileeṣẹ naa, Ọgbẹni Ifẹoluwa Daniel fi sita, eyi ti ẹda rẹ tẹ AWIKONKO lọwọ lo ti jẹ ko di mimọ pe odu ni Arabinrin Aminat Adisa, kii ṣaimọ f'oloko lagboole Amofin ni Naijiria.
Amofin to ja fafa, to si ni iwa ọmọluabi ati akikanju pẹlu wi pe o tun mu ẹsin lokunkundu ni Aminat Adisa, to si tun ni ọkan ati ẹmi irẹlẹ to fi n ba awọn eeyan ṣe.
Ọgbẹni Daniel sọ pe Amofin Adisa yoo darapọ pẹlu awọn Amofin mẹrin miran ti wọn ti n ba ileeṣẹ Pelican Valley naa ṣiṣẹ tẹlẹ, fun ajọṣepọ to dan mọran ati itẹsiwaju ileeṣẹ naa.
Siwaju sii lo sọ pe lati le tẹsiwaju ninu awọn eto ati ilana wọn ni ibamu pẹlu titẹle ofin orileede Naijiria lo fa a, ti wọn tun ṣe gba Amofin naa lati ṣiṣẹ pẹlu wọn.
Ile-ẹkọ alakọbẹrẹ Taoheed Islamiyya Nursery & Primary School Oke Odo to wa nipinlẹ Ekoo ni Aminat Ọlabisi ti bẹrẹ eto ẹkọ rẹ, ko to tẹsiwaju nile ẹọ girama ti Oke Odo to wa ni Alimọṣhọ, ipinlẹ Ekoo kan naa.
Latibẹ lo tun ti tẹsiwaju lọ si fasiti Ọbafẹmi Awolọwọ niluu Ile-Ifẹ, ipinlẹ Ọṣun nibi to ti kẹkọọ gba iwe ẹri nipa ofin. Bakan naa lo tun lọ si ile-ẹkọ ofin orileede Naijiria to wa niluu Adamawa, ipinlẹ Yola nibi to ti gboye (LL.B.) (Hons).
Ko tan sibẹ, Amofin Adisa wa lara awọn ajọ ati ẹgbẹ Amofin bii Chartered Mediator and Conciliator (ICMC NIGERIA), Gender Based Violence Respondent (Spotlight Initiative & WARIF) , to si tun ni iwe ẹri akọṣẹmọṣẹ (NGO MGT./FUND RAISING) atawọn miran.
Bẹẹ lo tun gba awọn ileeṣẹ Amofin bii Babatunde Fabunmi & CO. Abeokuta, ipinlẹ Ogun ati Adekọla Kareem Chambers, Jericho, niluu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ kọja.
No comments:
Post a Comment