Ọnarebu Oluọmọ di abẹnugọn ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun lẹẹkeji - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, June 20, 2023

Ọnarebu Oluọmọ di abẹnugọn ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun lẹẹkeji


Ọnarebu Ọlakunle Oluọmọ ni wọn ti pada dibo yan lati di abẹnugọn ile igbimọ aṣofin kẹwaa nipinlẹ Ogun lẹẹkeji.

Lonii, ọjọ Iṣẹgun tii ṣe Tusidee ni gbogbo awọn aṣofin ipinlẹ Ogun patapata dibo yan Oluọmọ lati jẹ olori wọn fun ile igbimọ naa.

Ọnarebu Musẹ la gbọ pe o kede Oluọmọ sita, nigba ti Ọnarebu Owodeh lati ẹkun Ijẹbu East si keji aba rẹ.

Fun awọn ti ko ba mọ, inu oṣu kẹfa, ọdun 2019 ni wọn kọkọ yan Ọnarebu Ọlakunle Oluọmọ gẹgẹ bi abẹnugọn, ko to tun di pe wọn pada yan-an lonii fun igbakeji.

Agbegbe Ifọ kinni ni Oluọmọ n ṣoju nile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa.

Ọnarebu Ajayi Bọlanle Latifat ni wọn tin dibo yan lati jẹ igbakeji abẹnugọn ile igbimọ aṣofin ọhun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI