Ọna ti NN|PC gba fi owo kun owo epo ko b'ofin mu - Falana pariwo sita - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, June 4, 2023

Ọna ti NN|PC gba fi owo kun owo epo ko b'ofin mu - Falana pariwo sita


Agbejọro araalu nni, Fẹmi Falana ti pariwo sita, o si jẹ ko di mimọ pe ọna ti ileeṣẹ elepo orileede Naijiria,
Nigerian National Petroleum Company Limited (NNPCL) gba fi owo kun owo ori epo ko ba ofin mu rara.

Falana, ẹni to tun jẹ gẹgẹ bii alẹnulọrọ ninu iṣẹ eto ofin orileede yii lo sọrọ naa lẹyin ipade pajawiri to ṣe pẹlu ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ, Nigeria Labour Congress (NLC) niluu Abuja.
 
O sọ pe ileeṣẹ ti ko ni aṣẹ ni NNPC jẹ, ti wọn ko si ni aṣẹ lati paṣẹ fun ijọ apapọ lori bi wọn ṣe gbe owo ori epo lọ soke.
 
O wa rọ ijọba apapọ lati ṣe agbeyẹwo ọwọngogo naa, ki wọn si wa ọna ti wọn yoo fi wa bi nnkan yoo ṣe dẹ araalu lọrun lakoko yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI