Ọmọ ọdun mẹsan ti mo ba laṣepọ lo dunkoko mọ mi - Baba agbalagba sọrọ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, June 14, 2023

Ọmọ ọdun mẹsan ti mo ba laṣepọ lo dunkoko mọ mi - Baba agbalagba sọrọ


Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Edo ti tẹ ọkunrin ẹni ọdun mọkandinlogoji kan, Sunday Ejeh, ẹni ti wọn lo fipa ja ibale ọmọdebinrin, ọmọ ọdun mẹsan ninu igbo, to si ti n ge ika jẹ.
 
Agbegbe kan ti wọn pe ni Ugbogi ni Ighobazuwa, ijọba ibilẹ Ariwa Ovia niṣẹlẹ ọhun ti waye laipẹ yii.
 
Nigba to n f'idi iṣẹlẹ ọhun mulẹ, agbẹnusọ f'awọn ọlọpaa ipinlẹ naa, Chidi Nwabuzor sọ pe otitọ ni, ati pe ẹgbẹta naira ni Sunday fun ọmọ naa lẹyin to huwa buruku naa tan.
 
Bẹẹ lo sọ pe ẹka ileeṣẹ wọn to n ri sọrọ iwa ọdaran ti bẹrẹ iwadii, wọn ti n fọrọ wa a lẹnu wo, igbesẹ to ni yoo kọgun si fifoju rẹ ba ile-ẹjọ. 
 
Nigba to n b'awọn akọroyin sọrọ, Sunday sọ pe iṣẹlẹ ọhun ti pẹ, o ni inu oṣu kin-in-ni, ọdun yii loun fipa ba ọmọ naa laṣepọ, ati pe oun ko mọ pe aṣiri maa pada tu sita.

Siwaju sii lo ni oun ko ṣe iru nnkan bẹẹ ri pẹlu ẹlomiran latigba naa.
 
“Inu oṣu kini ọdun yii ni iṣẹlẹ naa waye, ọmọ yii lo wa sile mi, to si ni ki n foun lowo, ki n ba oun laṣepọ. Mo ni rara, ṣugbọn o sọ pe oun maa pariwo ti mi o ba ṣe e.

“Ọmọ yii lo sọ pe oun maa pariwo wi pe mo fipa ba oun laṣepọ ti mo ba kọ lati ṣe nnkan toun n fẹ. Idi ree ti mo fi gba. Ẹgbẹrun kan ataabọ naira ni mo fun ko to maa ba tiẹ lọ.
 
Siwaju sii lo sọ pe awọn ọdọ adugbo ni wọn rago boun nigba toun n bọ lati inu oko lọsẹ to kọja, ti wọn si dana iya foun wi pe oun fipa ba ọmọ kekere kan laṣepọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI