Gbajugbaja onkọrin agbaye Afro nni, David Adeleke ti sọ pe gbogbo igba toun ba ji laaarọ, loun maa n bu sẹkun lori iku ọmọ oun, Ifeanyi to jade laye ni nnkan bi oṣu meloo sẹyin.
David Adeleke ti ọpọ awọn ololufẹ rẹ mọ si Davido lo sọ eyi ninu ifọrọwerọ kan to ṣe pẹlu Omega lori ayelujara.
Nibi ifọrọwerọ ọhun lo tun ti jẹ ko di mimọ pe ọpọ awọn eeyan lo n reti wi pe oun yoo gbe orin ibanujẹ jade nitori iku ọmọ oun naa, ṣugbọn toun pada gbe eyi to mi igboro titi jade.
“Mo maa n ṣafẹri ẹ lojoojumọ, omije maa n jade loju mi ni gbogbo aarọ ti mo ba ji, ko digba ti ẹ ba rii.
Bẹẹ lo tun sọ pe oun n mu ara le nitori pe oun gbọdọ maa daraya f'awọn ololufẹ oun kaakiri agbaye.
Iforọwerọ naa ree:
No comments:
Post a Comment