Ọga ọlọpaa patapata lorileede Naijiria, Olukayọde Ẹgbẹtokun ti sọ pe lati asiko yii lọ, ina jija ti di eewọ fun gbogbo ọlọpaa, lati ori oun, titi de ori ẹni to kẹyin ninu iṣẹ naa.
Ẹgbẹtokun sọ pe gbogbo ọlọpaa to ba n kọwọrin lọ lopopona lo gbọdọ duro nigba ti ina to n dari ọkọ ba ti da wọn duro.
Ọga ọlọpaa naa lo sọrọ yii lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii lakoko to ṣabẹwo si ọga agba ikọ Mobile Police Squadron.
Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe:
"Ẹ jẹ ki n pari ọrọ mi bayii wi pe awọn to ba n pa alaafia mọ gan-an ni awokọṣe alaafia. Awọn to jẹ pe ojuṣe wọn ni lati f'idi ofin mulẹ naa gbọdọ tẹlẹ ilana ati ofin orileede.
"Lai tẹlẹ ofin, a jẹ pe awọn ọlọpaa naa ko ni aṣẹ lati mu awọn to n tako ofin, tabi f'oju arufin winna ofin.
"Ju gbogbo rẹ lọ, ni ibamu pẹlu afojusun mi lati jẹ ki ileeṣẹ ọlọpaa naa maa tẹle ofin, mo wa pa a laṣẹ bayii pe gbogbo mọto akọwọrin ọlọpaa patapata, yala wọn n lọ sibi iṣẹlẹ pajawiri ni tabi wọn ko lọ, wọn gbọdọ duro fun ina to n dari ọkọ, bẹẹ si ni wọn gbọdọ tẹle ofin ina to n dari ọkọ. Mo jẹjẹ lati farajin fun aṣẹ yii, ki n si jẹ awokọṣe."
No comments:
Post a Comment