O ma ṣe! Awọn marun-un dagbere faye lọjọ Aiku ninu ijamba ọkọ l'Ondo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, June 12, 2023

O ma ṣe! Awọn marun-un dagbere faye lọjọ Aiku ninu ijamba ọkọ l'Ondo


Ko din ni eeyan marun-un ti wọn ti gba ekuru jẹ lọwọ ẹbọra ninu ijamba ọkọ to waye loju ọna Ikaram-Akoko, ijọba ibilẹ Akoko North-West, ipinlẹ Ondo lọjọ Aiku, Sannde ana.


Inu bọọsi elero mejidinlogun ti Toyota Hiace ti nọmba idanimọ rẹ jẹ
DKA 256 XY la gbọ pe awọn eeyan naa ti fẹmi wọn ṣofo lọjọ naa.

Ẹnikan ti iṣẹlẹ ọhun ṣoju rẹ, Niyi nigba to n sọrọ ṣalaye pe ọkan lara awọn taya bọọsi naa lo fọ lori ere asapajude, to si mu ki awakọ ọhun sọ ijanu rẹ nu.
 
Yatọ si awọn marun-un ti a gbọ pe wọn ku sinu ijamba naa, a gbọ pe awọn ero yooku to wa ninu bọọsi naa farapa yannayanna kọja sisọ.
 
Awọn to wa nitosi la gbọ pe wọn ranṣẹ s'awọn ẹṣọ aabo ijọba apapọ ti a mọ si Federal Road Safety Corps (FRSC), ẹka ti Ikarẹ-Akoko, ati awọn ọlọpaa ẹkun Oke-Agbẹ Akoko fun iranwọ.
 
Nipa ifọwọsowọpọ yii la gbọ pe wọn fi gbe awọn oku naa lọ si mọṣuari, ti wọn si ko awọn to farapa lọ si ọsibitu fun itọju to pe ye.
 
Ju gbogbo rẹ lọ, Ọba Andrew Mọmọdu tiluu Ikaram-Akoko, nigba to n sọrọ sọ pe ọpọ igba lawọn ti ranṣẹ si ijọba lati ṣe ohun to n da ọkọ duro fungba diẹ, eyi ti yoo di awọn awakọ lọwọ lati sare asapajude lopopona naa, lati le din ijamba ku.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI