O ku dẹdẹ ki Akinọla ko iyawo atawọn ọmọ rẹ lọ siluu Oyinbo ni wọn ṣaa pa l'Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, June 17, 2023

O ku dẹdẹ ki Akinọla ko iyawo atawọn ọmọ rẹ lọ siluu Oyinbo ni wọn ṣaa pa l'Ogun


Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti sọ pe ọwọ awọn ti tẹ awọn afurasi mẹta lori ẹsun ipaniyan, ti wọn si l’awọn mẹta naa ti n ṣalaye awọn ọrọ to le iwadii awọn lọwọ.

Awọn mẹta yii la gbọ pe wọn wa lara awọn to ṣa gbajumọ lanlọọdu kan, Akinọla Agbẹdẹ pa sinu ile ẹ to wa ni Ajuwọn, Akute, iyẹn nibi aala to pin ipinlẹ Ogun ati Ekoo papọ.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn l’awọn meji kan lo ji ounjẹ igbalodde ti wọn n pe ni Sharwama, tọwọ si tẹ wọn. Bi ọwọ ṣe tẹ awọn eeyan naa ni wọn ti fẹsun ole jija kan wọn, ko to di pe wọn foju wọn han kaakiri adugbo.

Nibi ti wọn ti n foju wọn han la gbọ pe Agbẹdẹ ti yọju sibẹ, to si lu ọkan lara wọn. Bo ṣe sọrọ buruku si wọn, to si ni ki wọn jawọ ni wọn l’awọn yẹn ti muu sinu, ti wọn si n ronu ohun ti wọn yoo ṣe fun un, bi ori ba ko wọn yọ.

Lara awọn agbaagba adugbo naa lo sọ pe ki wọn fi wọn silẹ lati maa lọ, ati pe wọn ko tun jẹ ṣe iru nnkan bẹẹ mọ.

A gbọ pe nigba ti wọn fi wọn silẹ, ni wọn lọ ba Agbẹdẹ, ti ṣeleri wi pe awọn yoo ge ọwọ to fi lu awọn danu, ko to di pe wọn ba ti wọn lọ.
Ere ni wọn l’Agbẹdẹ pe ileri naa, afi bo ṣe di ọjọ keji ti wọn l’awọn tọọgi ya bo ile rẹ pẹlu ada, ọbẹ, igi ati awọn nnkan ija oloro loriṣiriṣi, ti wọn si bẹrẹ sii luu.

Nibi ti wọn ti n lu la gbọ pe wọn tun ti bẹrẹ sii ṣaa lada, ti wọn si ṣa pa mọnu ile ti wọn ti ka a mọ.

A tiẹ gbọ pe iwaju iyawo Agbẹdẹ ni wọn ti ṣaa pa, ẹni ti wọn lo n bẹ awọn tọọgi naa lati foju aanu wo ọkọ oun, ki wọn ma si pa a, iyẹn lọjọ kẹjọ, oṣu kẹfa, ọdun ti a wa yii.

Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe asiko ti Agbẹdẹ n palẹmọ lati ko iyawo atawọn ọmọ rẹ lọ maa gbe niluu Oyinbo ni wọn ṣaa pa, koda, ti wọn sọ pe o ti ta ile ẹ ni miliọnu mẹwaa naira lati fi san owo irin ajo naa.

Ọmọlọla Odutọla to jẹ agbẹnusọ f’awọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun nigba to n f’idi iṣẹlẹ naa mulẹ sọ pe iwa buruku l’awọn ọdọ naa wu, ati pe mẹta pere lọwọ ṣi ba ninu wọn, to si ni iwadii ṣi n lọ lọwọ, ati pe ẹni ti aje ọrọ naa ba ṣi mọ lori yoo foju ba ile-ẹjọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI