Ṣe lọrọ di boolọ o yago lọna nigba ti wọn lawọn ajinigbe yawọ abule Awo to wa niluu Orile-Imọ, ijọba ibilẹ Ọbafẹmi Owode, ipinlẹ Ogun, nibi ti oṣiṣẹ aabo kan ti dagbere faye.
Ọjọru tii ṣe Wẹsidee la gbọ pe wọn yinbọn pa ẹṣọ aabo naa to jẹ ti ipinlẹ Ogun, iyẹn So Safe Corps, ẹni ti wọn pe orukọ rẹ ni Saheed Ogunrinde.
Ọmọ Abule naa ni wọn pe Saheed ti wọn yinbọn pa yii.
Wọn ni aṣọ awọn ẹṣọ ologun orileede yii lawọn ajinigbe naa wọ wọnu abule, ko to di pe awọn eeyan ta ileeṣẹ ọlọpaa atawọn ẹṣọ aabo So-Safe lolobo, ti wọn si gbera lati tọpinpin wọn.
Lara awọn ara abule naa to b'akọroyin sọrọ ṣalaye pe alẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee niṣẹlẹ ọhun waye. Wọn lawọn ajinigbe naa gbiyanju lati ji awọn eeyan to n ṣiṣẹ lọwọ ninu oko gbe, ṣugbọn ti wọn lawọn ẹṣọ aabo da wọn lọwọ kọ.
Ẹni naa sọ pe o ṣeni laanu wi pe awọn meji ni wọn ri jigbe salọ, ti wọn si pa awọn mẹta ko to di pe wọn na papa bora.
Ọga agba ileeṣẹ So-Safe Corps, Ọgbẹni Sọji Ganzalo nigba to n sọrọ sọ pe awọn oṣiṣẹ wọn lawọn ọlọpaa ranṣẹ e nigba ti olobo naa tẹ wọn lọwọ. O ni wọn ko ri ẹnikẹni lalẹ ọjọ naa, ṣugbọn ti wọn tun pada lọ laarọ ọjọ keji tii ṣe Wẹsidee.
Ganzalo tẹsiwaju pe nibẹ ni wọn ti fi ibọn koju ara wọn, ti ibọn si ba Saheed, ẹni tọpọ mọ si Ajura. O nibẹ ni wọn ti gbe ibọn ati foonu rẹ salọ.
Bakan naa lo fi kun ọrọ rẹ pe awọn ti sinku rẹ si ile to n gbe niluu Ajura.
No comments:
Post a Comment