Kayeefi nla gba a lọrọ iku ọga agba banki ẹyawo kan ti wọn pe ni SEAP Micro-Finance Bank, eyi to wa ni Ṣaki, Ọgbẹni Ṣọla Ogungbe ṣi n jẹ f'awọn araalu, paapaa awọn to gbọ si iṣẹlẹ naa.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ko si nnkan meji to mu ki Ṣọla gbẹmi ara rẹ lọsan gangan, to kọja owo ti awọn onibara banki naa gba, ti wọn ko si san pada.
Ile ti Ṣọla, ẹni ọdun mọkanlelogoji naa n gbe niluu Isẹyin, ipilẹ Ọyọ la gbọ o pokunso si l'Ọjọru tii ṣe Wẹsidee, ọsẹ ti a wa yii, gẹgẹ bi iroyin to tẹ wa lọwọ ṣe sọ.
Miliọnu kan naira la gbọ pe owo ti awọn eeyan ya ni banki ẹyawo SEAP ti Ṣọla ti jẹ alakoso rẹ, ti wọn si kọ lati san an pada lasiko ti wọn da.
Wọn ni Ṣọla gan-an lo ṣe iranwọ owo yii jade fun gbogbo awọn to ya owo ọhun.
Igba ti wọn lo yẹ ki awọn to ya owo naa da owo pada, ti wọn ko si da a pada lasiko, lo mu ki Ṣọla pinnu lati ma ṣe lọ si ibiṣẹ mọ titi digba ti awọn eeyan yoo fi da owo naa pada.
Ọkan lara awọn oṣiṣẹ banki naa la gbọ pe o pe iyawo Ṣọla lori foonu lati beere ọkọ rẹ, ati lati wa ṣalaye nipa owo to gbe jade sita f'awọn eeyan.
Wọn nigba ti iyawo Ṣọla maa pada de ile lalẹ, pẹlu erongba lati ṣalaye awọn to pe e lati fi ẹjọ sun oun, lo jẹ iyalẹnu nla fun un nigba to ba oku ọkọ rẹ loke ninu yara.
Ọkan lara awọn ọrẹ Ṣọla to ni ka f'orukọ boun laṣiri sọ pe aṣiṣẹ nla ni ọrẹ oun ṣe lati gb'ẹmi ara rẹ, ati pe o yẹ ko ti ṣalaye f'awọn ọrẹ rẹ, ki wọn si ba a wa ọna abayọ.
A gbọ pe wọn ti gbe oku Ṣọla lọ siluu Omu-Aran to wa nipinlẹ Kwara lati sin in sibẹ.
No comments:
Post a Comment