Mi o mọ pe mọto ti wọn jigbe ni wọn sọ pe ki n wa ba wọn gbe l'Ekoo - Austin - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, June 11, 2023

Mi o mọ pe mọto ti wọn jigbe ni wọn sọ pe ki n wa ba wọn gbe l'Ekoo - Austin


Adeolu Gbọlaruwa, Abẹokuta
 
Beeyan ba wa ni olu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun laipẹ yii, nibi ti ọga ọlọpaa, Ọlanrewaju Ọladimeji ti foju awọn afurasi ọdaran mẹrinlelogoji han f'awọn akọroyin, yoo mọ daju pe ojoojumọ ni iwa ọdaran n peleke sii.
 
Lara awọn ti ileeṣẹ ọlọpaa foju rẹ han ni Austin Omoh, ẹni ọdun mejilelọgbọn ti wọn sọ pe ko niṣẹ meji ju iṣẹ adigunjale lọ, ati pe oun nikan kọ lo n digunjale, bi ko ṣe pe wọn pọ lẹnu iṣẹ naa, ṣugbọn ti awọn yooku rẹ ti na papa bora.
 
Ọladimeji nigba to n sọrọ, ṣalaye pe obirin kan, Arabinrin Mary Iyiọla lawọnn adigunjale gba mọto lọwọ ẹ, ti wọn si gbe e salọ. O loju ẹsẹ ni obinrin ọhun ti gba teṣan ọlọpaa lọ lati fẹjọ sun, to si mu ki iṣẹ iwadii bẹrẹ.
 
Siwaju sii ni ọga ọlọpaa naa ṣalaye pe mọto Toyota Sequoia ti nọmba idanimọ rẹ jẹ AAA 631 HX ni wọn gba lọwọ Mary lọsan ganri.
 
Ninu iwadii awọn ọlọpaa ni wọn ti kofiri mọto ọhun si agbegbe Marọkọ n'ipinlẹ Ekoo, ti wọn si tọpinpin lọ sibẹ.
 
Si iyalẹnu wọn lawọn ọlọpaa da mọto naa duro, ṣugbọn ki oloju too ṣẹ ẹ, pupọ awọn to wa ninu mọto naa ni wọn sa bọ silẹ, ti wọn si juba ehoro, ṣugbọn to jẹ pe Austin nikan lọwọ tẹ.
 
Austin nigba to n sọrọ ṣalaye pe oun ko mọ awọn to ni mọto naa ri, ati pe niṣẹ ni wọn ranṣẹ pe oun lati wa a ba wọn wa mọto naa, lọjọ ti aṣiri tu.
 
O sọ pe ka loun mọ pe mọto ti wọn jigbe ni, oun ko nii tẹle wọn rara, ati pe ọgba Fẹla to pe ni 
 
"Awọn mẹta kan ni wọn wa ba mi wi pe ki n wa mu wọn lọ si Lẹkki, igba ti a n lọ ni ina da wa duro, ti awọn ọlọpaa si jade si wa. Wọn ni ka duro, nibi ti mo ti fẹẹ duro lawọn ti mo n gbe lọ si fọ bọ silẹ, ti wọn si salọ. Mẹta ni wọn, ẹnikan ṣoṣo ni mo si mọ laaarin wọn, Abẹla ni a maa n pe e.

"Iṣẹ agbero ti National lo n ṣe. Wọn lawọn n bọ lati African Shrine, wi pe awọn ko mọ ọna. Mọto Korope lemi maa n wa, ibẹ ni mo ti mọ Abẹla to pe mi.

"Ko pe mi bẹẹ rii. Ọmọ ọgbọn ọdun ni mi. Mi o ri iru mọto yii lọwọ wọn ri. Agege ni mo n gbe l'Ekoo, mo fẹ ki ijọba foju aanu wo mi, nitori pe mi o mọ ibi ti wọn ti ri mọto yii. Ẹ ṣaanu mi."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI