Mayọwa ati Ayọmide dero ẹwọn lori ẹsun 'Yahoo-Yahoo' n'Ibadan, ni wọn ba lorukọ ko ro wọn rara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, June 30, 2023

Mayọwa ati Ayọmide dero ẹwọn lori ẹsun 'Yahoo-Yahoo' n'Ibadan, ni wọn ba lorukọ ko ro wọn rara


Ọpọ awọn to gbọ nipa bi ile-ẹjọ giga t'ipinlẹ Ọyọ, eyi to wa niluu Ibadan ṣe ju gendekunrin mẹji kan ti orukọ wọn nii ṣe pẹlu ayọ sẹwọn lori iwa jibiti lo n ṣe ni kayeefi, ti wọn si n sọ pe aṣijẹ orukọ wọn n jẹ.
 
Ẹsun jibiti ori ikanni ayelujara ti a mọ si 'Yahoo-Yahoo' ni wọn sọ pe awọn mejeeji, Yusuf Nurudeen Mayọwa ati Muheez Adeṣhina Ayọmide fi n lo orukọ wọn, ti wọn si ni wọn gba ọpọ awọn alaimọkan.

Yatọ si awọn meji yii, ile-ẹjọ naa tun ju ọmọ ilẹ Ibo kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Wisdom Chibuzor sẹwọn lori ẹsun kan naa yii.

Ẹsun kan ṣoṣo la gbọ pe wọn fi kan Yusuf, eyi to nii ṣe pẹlu pipurọ gba owo, ti wọn si loo lodi s'ofin.

Awọn mẹtẹẹta yii ni wọn gba wi pe awọn jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn lotitọ niwaju Onidajọ Ladiran Akintọla.

Nigba to n gbe idajọ ọhun kalẹ, Onidajọ Akintọla paṣẹ pe ki Mayọwa lo fẹwọn oṣu mẹfa gbako gbara, tabi ko lọ san ẹgbẹrun lọna igba naira gẹgẹ bi owo itanran, bẹẹ lo tun ju Chibuzor ati Ayọmide sẹwọn oṣu mẹta-mẹta ọtọọtọ tabi ki wọn san ẹgbẹrun lọja ọgọrun-un kan naira ati ẹgbẹrun lọna aadọta naira gẹgẹ bi owo itanran lati fi rọpo ẹwọn wọn.
 
Ile-ẹjọ naa paṣẹ pe ki Mayọwa gbagbe miliọnu meje naira le diẹ (N7, 305, 978) ti wọn ba ninu apo ile ifowopamọsi ti GTB rẹ to ni nọmba 0209559041 s'apo ijọba apapọ. Bẹẹ tun ni yoo gbagbe mọto Toyota Camry Saloon atawọn nnkan miran ti wọn tun gba lọwọ ẹ sọwọ ijọba.
 
Bakan naa lo ni ki wọn da gbogbo nnkan ti wọn gba pada f'awọn ti wọn lu ni jibiti.




No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI