Makinde fi orukọ awọn meje to fẹẹ lo fun ipo Kọmiṣanna ranṣẹ sile igbimọ aṣofin - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, June 22, 2023

Makinde fi orukọ awọn meje to fẹẹ lo fun ipo Kọmiṣanna ranṣẹ sile igbimọ aṣofin


Gomina Ṣeyi Makinde ti ipinlẹ Ọyọ ti fi orukọ awọn meje kan ranṣẹ sile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa lati ṣagbeyẹwo wọn fun ipo kọmiṣanna to ṣetan lati yan.
 
Ọjọru tii ṣe Wẹsidee, ọsẹ yii la gbọ pe Gomina Makinde fi awọn orukọ naa ranṣẹ sile igbimọ aṣofin.

Awọn naa ni, Ọgbẹni Adeniyi Adebisi, Ọgbẹni Akinọla Ojo, Ọjọgbọn Musibau Babatunde, Ọjọgbọn Daud Ṣangodoyin, Ọgbẹni Ṣeun Aṣhamu, Alaaja Fausat Jọkẹ Sanni ati Arabinrin Toyin Balogun, toun ṣẹṣẹ de laaarin wọn.
 
Ninu awọn orukọ yii la gbọ pe mẹfa ninu wọn ti jẹ kọmiṣanna tẹlẹ ni saa akọkọ gomina, to si tun fẹẹ pada lo wọn lẹẹkeji.
 
Ọkan lara awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin naa lo tu aṣiri yii, to si loun ti ri iwe orukọ awọn meje naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI