Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin ni iṣẹlẹ ọhun ṣi n jẹ iyalẹnu ati kayeefi nla lori bi ọkan lara awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Kaduna ṣe jade laye lẹyin ọjọ kẹrin ti wọn bura f'oun at'awọn akẹgbẹ rẹ.
Ọnarebu Garba Madami ti wọn lo n ṣoju ẹkun Chikun nile igbimọ aṣofin kẹwaa ipinlẹ naa ni wọn lo ku lẹyin ti aisan kan deedee kọ luu.
Ọsibitu ijọba to wa ni Kaduna ni wọn sọ pe ọkunrin naa dakẹ si lọjọ kẹtadinlogun, oṣu kẹfa, ọdun 2023, iyẹn ọjọ Abamẹta tii ṣe Satide, ana, gẹgẹ bi akọwe iroyin gomina, Mohammed Shehu ṣe sọ.
Oloogbe naa ni wọn lo ti figba kan ri alaga ijọba ibilẹ Chikun, to si tun ti figba kan ri jẹ kọmiṣanna fọrọ eto agbekalẹ ati iṣuna, Planning and Budget fun ipinlẹ naa.
Wọn loun tun ni oludamọnran pataki lori ọrọ eto oṣelu fun Gomina Patrick Yakowa toun naa ti doloogbe.
No comments:
Post a Comment