Iroyin ibanujẹ lo sọ niluu Gbagura to wa ni Abẹokuta ipinlẹ Ogun, nigba ti Agura, Ọba Babajide Sabur Bakre tẹri-gbaṣọ.
Alẹ ana, Ọjọru, Wẹsidee ni Kabiyesi naa jade laye lẹyin aisan rampẹ ti wọn lo kọluu lojiji.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni ile ni Kabiyesi naa wa to fi dubulẹ aisan lojiji, to mu ki wọn sare gbe e lọ si ọsibitu kan niluu Abẹokuta.
Lati ọsibitu naa la gbọ pe wọn ti sare gbe e digbadigba lọ si ọsibitu miran niluu Ekoo lati doola ẹmi rẹ.
Niṣe la gbọ pe ọrọ yiwọ nigba ti Kabiyesi naa ki aye pe o digboṣe, nigba ti ọlọjọ de.
Inu oṣu karun-un, ọdun 2019 ni Gomina ana n'ipinlẹ Ogun, Sẹnetọ Ibikunle Amosun gbe ade ati ọpa aṣẹ fun Ọba Bakre gẹgẹ bii Agura tiluu Gbagura kẹsan.
Kabiyesi naa jade laye lẹni ọdun mọkanlelọgọta.
Alẹ Ọjọru Wẹsidee naa ni wọn gbe oku Kabiyesi pada si aafin lati tete ṣeto isinku rẹ laaarọ oni, nilana Musulumi.
Nigba to n fidi iroyin ọhun mulẹ, akọwe aafin, Oloye Razaq Adeṣọla Obe jẹ ko di mimọ pe otitọ ni.
"Osi ilu Ẹgba ati Balogun Ibadan ti Gbagura niluu Abẹokuta ti paṣẹ fun mi lati fi to o yin leti pe Alayeluwa, Ọba Saburee Babajide Bakre, Jamolu keji, Agura tiluu Gbagura ti jade laye, o si ti lọ ba awọn babanla rẹ lonii ọjọ kẹrinla, oṣu kẹfa, ọdun 2023.
"Ki Ọlọrun tẹ Kabiyesi si afẹfẹ rere"
No comments:
Post a Comment