Olu tiluu Orile-Ilawọ, Ọba Ọjọgbọn Oluṣẹgun Alexander Macgregor ti gba gbogbo ọmọ ati olugbe orileede Naijiria lamọran lati ni ọpọlọpọ suuru fun Aarẹ tuntun, Aṣiwaju Bọla Ahmẹd Tinubu, to si loun nigbagbọ pe baba naa yoo ṣe daadaa ninu iṣejọba rẹ.
Kabiyesi, Ọba Macgregor lo sọrọ naa niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun l'Ọjọ Ẹti tii ṣe Furaidee, ọsẹ yii nibi akanṣe eto ti ẹgbẹ awọn akọroyin nipinlẹ Ogun gbe kalẹ.
Nigba to n sọrọ nipa owo iranwọ ori epo rọbii t'ijọba yọ danu laipẹ yii, Kabiyesi naa sọ pe lara igbesẹ akikanju, ati ilana iṣejọba rere ni, ati pe lati le mu idagbasoke ba eto ọrọ aje orileede yii ni.
O ni Aarẹ Tinubu mọ ipenija to n koju orileede Naijiria ju ẹnikẹni lọ, to si mọ ọna abayọ si iṣoro naa, ati pe lara awọn orileede to ṣoro lati ṣakoso rẹ lagbaye ni Naijiria jẹ
Siwaju sii lo sọ pe Aarẹ Tinubu ni gbogbo ohun amuyẹ lati tukọ orileede yii de ibi rere, nitori pe o ni ọkan lati lọ ba gbogbo awọn alẹnulọrọ ti yoo dide lati wa ọna abayọ.
Ninu ọrọ rẹ, Kabiyesi sọ pe: “Adura mi si Aarẹ Tinubu ni pe ki Ọlọrun fun un ni okun ati agbara, ati ọkan lati koju ipenija orileede Naijiria. Ki Ọlọrun fun un ni agbara lati mu awọn ileri rẹ ṣẹ fun gbogbo ọmọ Naijiria.
“Naijiria jẹ orileede kan to ṣoro lati ṣakoso rẹ. Ko si ẹlomiran to dara to Bọla Ahmẹd Tinubu, to mọ ipenija, to si mọ ọna ti yoo gba lati ba awọn alẹnulọrọ sọrọ lati mu ọna abayọ wa fun awọn ipenija naa.”
Bakan naa lo gba Tinubu lamọran, lati ma ṣe gbagbe awọn ileri rẹ fun ọmọ Naijiria, ati pe ko tubọ maa ranti 'Emilokan' lo fi polongo fun idagbasoke ilu.
“Ko gbọdọ agbegbe awọn ileri rẹ nigba to wa siluu Abẹokuta nibi to ti sọ pe 'Emi lo kan', ati pe ni bayii, 'Awa lo kan' lati beere lọwọ ẹ. Mo nigbagbọ daadaa wi pe yoo mu awọn ileri rẹ ṣẹ.
“O ni ọpọ awọn eeyan to yii kan, o ni si ọkan ati ọgbọon lati ri awọn to kaju oṣuwọn, ti wọn ni lakaaye. O jẹ ẹnikan to mọ bi wọn ti n wa awọn ọlọgbọn eeyan. Awọn ọmọ Naijiria ni lati ṣe suuru fun un, ki wọn si gbauruku tii nipa adura. O maa fẹẹ nira, ṣugbọn asiko to dara ṣi n bọ.”
No comments:
Post a Comment