Ọrọ buruku toun tẹrin nigba tọwọ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun tẹ gendekunrin kan, Kẹhinde Adesọgba Adekusibẹ, ẹni to loun yoo pa gbogbo awọn ẹya Igbo to wa nilẹ Yoruba patapata, iyẹn latari ikorira to ni si wọn.
Pakopako ni Kẹhinde n wo, nigba to de agọ ọlọpaa, to si n bẹbẹ wi pe iṣẹ eṣu ni, ati pe aṣiwi lasan lọrọ ileri toun sọ jade lẹnu, to si ni ki wọn ṣe oun jẹjẹ.
Gẹgẹ bi agbẹnusọ f’awọn ọlọpaa ipinlẹ naa, Yeẹmisi Ọpalọla Ọlawọyin ṣe sọ, o ni ori ikanni ayelujara abẹyẹfo ti a mọ si Twitter ni Kẹhinde ti ṣeleri naa sita gbangba, to si ni k’awọn Igbo maa mura silẹ fun ọjọ iku wọn to de.
Agbẹnusọ agba fun ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria, Olumuyiwa Adejọbi ninu ọrọ tiẹ toun naa kọ sori ikanni Twitter ọhun l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, jẹ ko di mimọ pe ọrọ to le da ogun nla silẹ ni Kẹhinde sọ, ati pe o tako ilana lilo ikanni ayelujara.
O ni kete ti ileeṣẹ ọlọpaa ti ri ohun ti Kẹhinde kọ ọrọ naa lọjọ kejidinlogun, oṣu karun-un, ọdun 2023 wi pe “Ẹ jẹ ka pa gbogbo awọn Igbo to wa nilẹ Yoruba. Ẹ jẹ ka gba wọn danu nilẹ Yoruba. Mo ni ikorira fun awọn eeyan yii pẹlu itara. W|on buru. Wọn ko fẹran wa. Ẹ jẹ ki awa naa korira wọn pada.” ni wọn ti bẹrẹ iwadii.
Siwaju sii lo ni agbegbe kan niluu Ileṣa lọwọ ti tẹ ẹ, nibi to sapamọ si, ati pe o ti jẹwọ funra rẹ. O fi kun un wi pe yoo foju ba ile-ẹjọ lẹyin ti iwadii ba tubọ pari.
No comments:
Post a Comment