Bi gbogbo ọmọ orileede Naijiria jakejado agbaye ṣe ṣajọyọ ayajọ ọdun iṣejọba awarawa ti a mọ si June 12, bẹẹ naa ni Aarẹ Bọla Ahmẹd Tinubu ti sọ pe Oloogbe MKO Abiola gbagbọ ninu eto isẹjọba tiwantiwa, to si bọwọ fun ofin, ṣugbọn awọn ikọ ologun ṣekupa lai bọwọ fun ẹtọ ọmọniyan.
Aarẹ Tinubu lo sọrọ naa lasiko to n bawọn ọmọ Naijiria sọrọ laaarọ oni, ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kejila, oṣu kẹfa, ọdun 2023, nibi to ti gboriyin fun MKO Abiọla, to si lo fi gbogbo ohun to ni ja fun ominira orilẹede Naijiria.
Bakan naa lo gboriyin fun iyawo MKO Abiola, iyẹn Kudirat Abiola fun atilẹyin rẹ, to fi mọ Pat Alfred Riwane ati Ọgagun Shehu Musa Yaradua to ṣapejuwe pe wọn ja fitafita fun ẹtọ ọmọniyan lasiko June 12, ki ifẹ awọn araalu le ṣẹ.
Aarẹ Tinubu ni awọn ọmọ Naijiria ko gbọdọ ko iyan ominira ijọba tiwantiwa kere nitori awọn araalu to wa nigba ologun le sọ iriri wọn.
Tinubu ni ki awọn araalu ki ara wọn ku oriire lati ri ọjọ oni nitori o ti pe ọgbọn ọdun ti awọn araalu tuyaya jade lati dibo fun ẹni ti ọkan wọn fẹ.
‘‘A ko gbọdọ fi ijọba tiwantiwa ṣere rara, bo tilẹ jẹ pe eto idibo naa ko lọ jaara, amọ ijọba tiwantiwa lo dara julọ fun eto ijọba laye yii.
Bakan naa lo fikun un pe awọn araalu gbọdọ mọ riri ijọba tiwantiwa nitori awọn eniyan ko mọ iriri ijọba tiwantiwa naa afi igba ti wọn ba padanu rẹ.
Ninu ọrọ rẹ lori idibo sipo aarẹ to waye ni ọdun 2023, aarẹ Tinubu gboriyin fun awọn araalu to jade lati dibo fun ẹni ti ọkan wọn fẹ.
O ni eyi fihan pe awọn araalu mọ riri ijọba tiwantiwa ati yiyan ẹni ti wọn fẹ si ipo.
Siwaju sii lo ni idunu eto iṣejọba ni ki awọn to ba bori ki wọn dunnu ati awọn to kuna ki wọn gba fun ori. O ni ẹni ti ko ba le fi ara da ijakulẹ ko lee jẹ adun jijawe olubori.
Bakan naa lo ni ki awọn ti esi idibo ko ba lara mu gba ileẹjọ lọ, ki wọn si ni igbẹkẹle eto idajọ ni Naijiria.
‘‘Eto idajọ to gbooro lo le mu eto ijọba tiwantiwa gbooro si’’
Ninu ọrọ rẹ, Tinubu ni ohun kan pato to n gbe eto iṣejọba tiwantiwa ro ni eto idajọ to gbooro fun awọn araalu.
Tinubu ni ohun ti bẹrẹ awọn igbesẹ lati mu ki eto idajọ gbooro si lorilẹede Naijiria.
O ni ohun akọkọ ti oun ṣe lati ṣe afikun iye ọjọ ori ti awọn adajọ yoo ma fi ẹyinti lorilẹede Naijiria.
Aarẹ ni eyi yoo mu ki eto ijọba tiwantiwa gbooro si, ti oun si ni awọn eto miran lati mu idagbasoke ba eto idajọ ni Naijiria.
‘‘Mo mọ pe yiyọ owo iranwọ epo bẹntirol, ''Fuel Subsidy'' fa inira fun awọn araalu amọ...’’
Aarẹ Tinubu ni ki awọn araalu ma binu lori owo iranwọ epo bẹntirol ti wọn yọ amọ o ni eyi pọn dandan nitori awọn kan ti wọn n ja orilẹede Naijiria lole.
Bakan naa lo ni ki awọn araalu fi ara da asiko yii nitori wọn yoo jere rẹ nitori awọn ohun meremere ti yoo jade lati ibẹ.
Aarẹ Tinubu wa ṣeleri fun awọn araalu pe inira ti yiyọ epo bẹntirol yoo mu de ba wọn yoo dopin ni ijọba oun.
‘‘Maa ri pe eto irinna lorilẹede Naijiria rọru fun awọn ara ilu.
‘‘Bakan naa ni ipese eto ẹkọ to gbooro yoo wa fun awọn araalu, eto iwosan to peye, ina ijọba ni pẹṣẹ ati igbayegbadun awọn araalu.’’
‘‘Mo ṣẹlẹri lati mu gbogbo ohun ti mo sọ pe maa ṣe fun awọn ọmọ Naijiria wa si imuṣẹ’
Ni ipari ọrọ rẹ, aarẹ Tinubu ni ki awọn ọmọ Naijiria ni igbagbọ ninu iṣejọba oun nitori igba yoo yi pada fun awọn ọmọ Naijiria.
O ṣẹlẹri lati ri pe igbayegbadun yoo de ba awọn ọmọ orilẹede Naijiria.
‘‘Ma ri pe otitọ jọba, idọgba waye ni Niajiria, bakan naa ni idajọ ododo yoo di igbelarugẹ lorilẹede Naijiria.’’
‘‘Bakan naa ni awọn araalu yoo ni igbagbọ ninu orilẹede Naijiria, ti inu wọn yoo si dun lati jẹ ọmọ Naijiria.’’
Aarẹ Tinubu pari ọrọ rẹ nipa kiki awọn ọmọ Naijiria ku oriire ayajọ ọjọ iṣejọba tiwantiwa pẹlu adura pe omiran ati idunnu ko ni dagbere lorilẹede Naijiria.
No comments:
Post a Comment