Jonathan tu aṣiri ipade to lọ ṣe pẹlu Tinubu ni l'Abuja - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, June 14, 2023

Jonathan tu aṣiri ipade to lọ ṣe pẹlu Tinubu ni l'Abuja


Aarẹ tẹlẹri lorileede Naijiria, Goodluck Ebele Jonathan ti tu aṣiri idi pataki to fi lọ ba Aarẹ Bọla Ahmẹd Tinubu ṣe ipade papọ nile agbara orileede yii, iyẹn Aso- Rock to wa niluu Abuja.

Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee ni Jonathan lọ ba Tinubu, ti wọn si wọle ṣe ipade.

Ṣugbọn Jonathan, nigba to n sọrọ lori ohun to lọ ṣe, o sọ pe ipade apero to nii ṣe pẹlu iwe ofin, iyẹn Constitutional Referendum to fẹẹ waye lorileede Mali loun lọ ṣalaye rẹ fun Aarẹ Tinubu.
 
Ọkan pataki lara awọn ti yoo sọrọ nibi apero naa ni Jonathan jẹ ninu ajọ Economic Community of West African States (ECOWAS), ti yoo si tun kopa ni Mali.
 
Ọjọ kejidinlogun, oṣu kẹfa, ọdun ti a wa yii ni apero ọhun yoo waye, ohun si ni yoo jẹ atẹgun si eto idibo to n bọ ninu oṣu keji, ọdun 2024.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI