Ika abamọ nla ni baale ile ẹni ọdun mejilelogoji kan, Tunde Alabi ti wọn sọ pe ko niṣẹ meji ju ko maa ta ibọn lọ, ati pe ọna kan ṣoṣo to mọ lati maa fi ri owo gidi niyẹn nigbesi aye rẹ.
Gẹgẹ bi Yẹmisi Ọpalọla to jẹ agbẹnusọ f'awọn ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ṣe ṣalaye lakoko to n foju Tunde ati awọn ẹmẹwa rẹ to n ta ibọn fun han f'awọn akọroyin, o ni kii ṣe Tunde lọwọ kọkọ tẹ, bi ko ṣe iṣẹ iwadii lo tu aṣiri rẹ sita.
O ni Akano Ọlasunkanmi, ọmọ ogun ọdun ati Mọnsuru Ali toun jẹ ọmọ ọdun marundinlọgbọn lọwọ kọkọ tẹ ni ikorita opopona marosẹ Okepa Osu nipinlẹ Ọṣun.
A gbọ pe ori ọkada ni Ọlasunkanmi ati Mọnsuru wa lọjọ kẹtadinlogun, oṣu kẹfa, ọdun yii wa, ko to di pe awọn ọlọpaa da wọn duro lati yẹ wọn wo, to si jẹ iyalẹnu nigba ti wọn ba ibọn ilewọ lọwọ wọn.
Nibi ti wọn ti n ka boroboro ni Ọlasunkanmi ti jẹwọ wi pe oun loun ni ibọn na, ati pe ẹnikan ti n jẹ Tunde lo ta a foun ni ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira.
Ọlasunkanmi lo jẹwọ pe Agbẹdẹ Quarters, Toro Road, Mọdakẹkẹ ni Tunde n gbe, nibẹ lo si ti n ṣiṣẹ Wẹda to fi n boju.
Nigba tọwọ tẹ Tunde, ọta ibọn kan, ati ibọn loriṣiriṣi mọkanla ni wọn ba lọwọ ẹ.
Ọpalọla ni awọn mẹtẹẹta yoo foju ba ile-ẹjọ lẹyin ti iwadii ba tubọ pari lori wọn laipẹ.
No comments:
Post a Comment