Ileeṣẹ ọlọpaa orileede Naijiria ti kede Arabinrin SP Ọmọlọla Odutọla gẹgẹ bii Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ogun tuntun, ti yoo maa gbẹnusọ fun wọn nipa awọn ohun to n ṣẹlẹ kaakiri.
Ọmọlọla Odutọla lo gba ipo naa lọwọ Abimbọla Oyeyẹmi, ẹni to ti lọ bii ọdun mẹfa le diẹ gbako n'ipinlẹ naa.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ogbontarigi akọṣẹmọṣẹ nipa eto ofin ni wọn pe Odutọla, ẹni ti wọn lo wọ iṣẹ ọlọpaa lọdun 2012, pẹlu ipo Cadet Assistant Superintendent of Police.
A gbọ pe Odutọla kẹkọọ gboye nipa iṣẹ agbẹjọro, to si tun ni imọ nipa ọrọ ọdaran ati oṣiṣẹ aabo to dantọ.
Obinrin yii, gẹgẹ bi a ṣe gbọ fẹran ere idaraya pupọ, bẹẹ lo ti ṣiṣẹ n'ipinlẹ Ondo, to si jẹ agbẹnusọ akọkọ fun ẹka Maritime Command ni Force Headquarters Annex, Kam Salem House, Ọbalende, l'Ekoo.
Fasiti Ọlabisi Ọnabanjọ to wa niluu Agọ-Iwoye, ipinlẹ Ogun ni Odutọla ti kẹkọọ gboye nipa ofin, ko to tẹsiwaju ni fasiti ipinlẹ Ekoo, nibi to ti ṣe Masters rẹ ninu ẹkọ Criminology.
No comments:
Post a Comment