Ileeṣẹ eleto aabo ijọba ipinlẹ Ogun ti sọ pe ọwọ awọn ti tẹ awọn meji kan ti wọn ko niṣẹ meji to kọja idigunjale lọ, ati pe asiko ti wọn lọ digun ja ileeṣẹ gaasi kan lọwọ palaba wọn segi.
Gẹgẹ bi agbẹnusọ ileeṣẹ aabo naa ti a mọ si Ogun State Community Social Orientation and Safety Corps, iyẹn So-Safe Corps, Ọgbẹni Mọruf Yusuf ṣe ṣalaye, o ni opin ọsẹ to kọja lọwọ tẹ wọn.
Yusuf
ni nnkan bi aago mọkanla aarọ, ọjọ Abamẹta tii ṣe Satide ni awọn
adigunjale yawọ ileeṣẹ gaasi naa, iyẹn Green Fuel Company to wa ladugbo
Estate, Onipanu, ijọba ibilẹ Ado-Odo Ọta.
O
sọ pe ibi ti wọn ti n ge awọn waya ina ati ọpa epo ileeṣẹ gaasi naa
l'aṣiri wọn ti tu, ti ọwọ si tẹ wọn loju ẹsẹ ti wọno fẹẹ gbiyanju lati
na papa bora.
Siwaju
sii ni agbẹnusọ naa jẹ ko ye wa pe ọkada Bajaaji ti nọmba idanimọ rẹ jẹ
TRE 461VL ati ọkada Honda ti nọmba tiẹ jẹ AAB 495VE ti wọn gbe lọ jale
ọhun ni wọn gba lọwọ wọn nibẹ.
Bakan
naa lo fi ye wa pe, ọga awọn, Olusọji Ganzallo ti paṣẹ pe ki wọn ko
awọn mejeeji, pẹlu awọn ohun ti wọn gba lọwọ wọn lọ si teṣan ọlọpaa ẹkun
Onipanu fun iwadii kikun.
No comments:
Post a Comment