Ijọba Naijiria tọwọ bọwe adehun pẹlu ijọba Korea lati wa iṣẹ f'awọn ọdọ ti ko din ni miliọnu kan - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, June 27, 2023

Ijọba Naijiria tọwọ bọwe adehun pẹlu ijọba Korea lati wa iṣẹ f'awọn ọdọ ti ko din ni miliọnu kan


Ijọba orileede Naijiria ti sọ pe gbogbo eto lo ti fẹẹ pari fun ijọba Naijiria lati da iṣẹ ti ko din ni miliọnu kan silẹ fun gbogbo awọn ọdọ, paapaa awọn ọdọ ti ko ri nnkan-ṣekan.
 
Kashim Shettima to jẹ igbakeji Aarẹ Naijiria lo fidi ọrọ yii mulẹ lọjọ Aje tii ṣe Mọnde, ana, to si lawọn ti ṣepade pẹlu awọn aṣoju ijọba orileede Korea.
 
Ninu atẹjade naa ti Oluṣhọla Abiọla to jẹ alakoso eto iroyin fun igbakeji aarẹ buwọ lu sọ pe awọn aṣoju aarẹ Yoon Yeol ti Jang Sungmin lewaju wọn ni wọn jọ sọ asọyepọ naa.
 
Shettima ni ajọṣepọ to wa laaarin Naijiria ati Korea ti pẹ nitori igbọra-ẹni ye ati igbagbọ ti wọn jọ ni ninu ara wọn.
 
“Ọpọ awọn ileeṣẹ to wa lati Korean ni wọn n ṣiṣẹ lorileede Najiria, paapaa lẹka eto afẹfẹ gaasi. Mẹfa ninu ileeṣẹ reluwee LNG wa lo jẹ pe awọn ileeṣẹ Korea lo ṣe wọn.
 
“A ti farajin fun ajọṣepọ to lọọrin laaarin ara wa. A nilo lati kọ ohun to pọ lara orea, paapaa lẹka eto ṣiṣe nnkan ati eto ọrọ agbẹ. Itan aṣeyọri lẹ jẹ, ti ẹ si jẹ awokọṣe fun gbogbo awọn orileede ti wọn ṣẹṣẹ n dagba bọ."

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI