Oluwo tiluu Iwo, Ọba AbdulRọsheed Adwwale Akanbi, Telu kin-in-ni ti sọ pe Ifa ko lagbara lati paṣẹ fun gomina ipinlẹ kan ko to yan ọba siluu.
Kabiyesi sọ pe Ifa kọ lo n yan Ọba nilẹ Yoruba,bi ko ṣe pe ẹni ti gomina ba fẹran ni wọn n gbe sori ipo ọba, eyi to loo ti wa latigba ti alaye ti da aye.
Ọba Akanbi lo sọrọ yii ninu Ifọrọwerọ to ṣe pẹlu awọn akọroyin, bi ayẹyẹ ọdun kẹjọ rẹ lori itẹ, ati gẹgẹ bi ọba ṣe n sunmọ etile.
Bi wọn ba n ka awọn ọba to gbajumọ daadaa lorileede Naijiria, paapaa nilẹ Yoruba lasiko yii, odu ni Oluwoo tiluu Iwo, kii ṣaimọ f'oloko, to si wa lara awọn ọba ti kii fẹ irẹjẹ nibikibi.
Ninu ọrọ rẹ, Ọba Adewale Akanbi sọ pe
"Ẹ sọ ọba kan ṣoṣo ti Ifa mu nilẹ Yoruba fun mi. Ẹni ti gomina ba ti yan naa ni Ọlọrun ti yan lati jẹ ọba. Ko si ọba kan nilẹ Yoruba lasiko yii to le sọ pe Ifa lo yan oun.
"Lẹyin ti gomina ba ti yan ẹ, lo ṣẹṣẹ le sọ pe o di ọba. Ifa ko lagbara lori gomina. Boya ki n sọ pe ere Yoruba ti ẹ maa n wo ti pọ ju ni. Koda, nigba awọn baba-nla wa, ẹni to ba lagbara julọ lasiko naa ni wọn maa fi n jẹ ọba nigba yẹn.
"Nigba ti mo de, mi o tiẹ mọ gomina ri rara, nitori pe mo ṣẹṣẹ de lati Canada ni, ṣugbọn mo sọ fun gbogbo awọn oludije ti wọn tiẹ lowo lọwọ, ti wọn tun gbajumọ gidi nigba yẹn pe emi ni ipo ọba naa kan.
"Mo ni koda, ki wọn mọ Barack Obama ati gomina ri, ko le yi ohunkohun pada, nitori pe emi ni ipo ọba Oluwo tiluu Iwo kan.
"Bi Olodumare ba fẹẹ ṣiṣẹ Rẹ, ko sẹni to le ye rara bi yoo ṣe ṣiṣẹ ọwọ Rẹ. Ko ju bi oṣu diẹ ki n di ọba ni Ọlọrun la ọna. Mi o mọ gomina ri tẹlẹ, ko too to ọjọ tki wọn kede mi.
"Nnkan bi aago kan oru ọjọ naa ni mo pade gomina, Ọlọrun si pari iṣẹ Rẹ, ko ju bẹẹ lọ. Iṣẹ Olodumare ni, Ọba ilẹ gbogbo Yoruba, Ọba awọn baba-nla wa, ati pe ko sẹni to le ye. Nigba ti Ọlọrun ba mu ọba kan wa, o mu un wa nitori idi pataki kan ni.
No comments:
Post a Comment